Muhammadu Buhari: Wo kókó méje tí Aàrẹ Buhari mẹ́nubà lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀

Buhari

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti n fesi si awọn ọrọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Channels Television gbe jade lọjọru.

Lara awọn nkan to mẹnuba ni pe oun ko fọwọ si idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ.

Bakan naa lo ni ijọba apapọ ko ni i jawọ ninu dida awọn oju ọna fun awọn maalu pada.

O ni igbesẹ naa nikan lo le fi opin si ija to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Nigba to n fesi si ọrọ yii, olori ẹgbẹ Afenife, Oloye Ayo Adebanjo sọ pe nkan ti ko bojumu ni aarẹ sọ.

O ni a fi ki Naijiria paarọ ofin to n lo ṣaaju idibo mira, "bibẹẹkọ abẹ isinru lao ku si".

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Adebanjo sọ pe "iparun nla gba a ni fun Naijiria bi Buhari ṣe sọ pe oun ko ni oye nipa atunto Naijiria ti awọn eeyan n pariwo rẹ".

Ninu ọrọ ti ẹ naa, Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic party, Dokita Iyorchia Ayu sọ pe o daju bayii pe eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria dun mọ Buhari ninu.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Bakan naa lo sọ pe bi aarẹ sẹ kọ̀ lati jawọn ninu idasilẹ oju ọba fun awọn maalu fihan pe ko ni ọgbọn atinuda.

Wo kókó méje tí Aàrẹ Buhari mẹ́nubà lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari to n tuko orilẹ-ede Naijiria lo t kopa Kókó méje nínú ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó wáyé láàárín ààrẹ Muhammadu Buhari àti ilé iṣẹ́ Channels TV

A kò lè déédé fi Nnamdi Kanu sílẹ̀ - Ààrẹ Muhammadu Buhari

Àkọlé fídíò, O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ìṣèjọba tó wà lóde lábẹ́ ìdarí òun ti fún Nnamdi Kanu, ẹni tí ó jẹ́ olórí àwọn tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra (IPOB) ní àǹfààní láti wá wí tẹnu rẹ̀ nílé ẹjọ́.

Nnamdi Kanu ni ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá láti ọdún 2021.

Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lórí ìlérí tó ṣe fún àwọn àgbàgbà ẹkùn Gúúsù Ìlà Oòrùn, Ààrẹ Buhari ní òun kìí dá sí ọ̀rọ̀ ẹ̀ka ìdájọ.

Lórí iná ọba, Ààrẹ Muhammadu Buhari bu ẹnu àtẹ́ lu fífi sí àkóso ẹ̀ka ọlọ́danni.

Ààrẹ kọminú pé kò sí orílẹ̀ èdè tó lè gòkè láì ní àwọn ohun amáyérọrùn bí i iná mọ̀nàmọ́ná, ọ̀nà tó já gaara àti ìrìnà ojú irin.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Lori ẹyawo ilẹ China, Aarẹ ni ẹnikẹni to ba ṣetan lati ya orile ede Naijiria lowo ni aaye wa fun lati ṣe bẹẹ.

Bakan naa lo ki awọn ọmọ orilẹ ede laya lati ma foya lori pe Naijiria n woko gbese.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ní òun kò ní kéde ẹni tí ó wu òun láti jẹ ààrẹ lẹ́yìn tí òun bá kúrò lórí oyè.

Ó ní ó ṣeéṣe kí aburú ṣẹlẹ̀ si ti òun bá kéde rẹ̀ kí àkókò ìdìbò tó tó.

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Bákan náà ni Ààrẹ rọ àwọn ọ̀dọ́ láti máa dúró dé kí ìjọba pèsè iṣẹ́ fún wọn lẹ́yin tí wọ́n bá parí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Ó ní ẹni tí ó bá lọ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbọ́dọ̀ lè ronú ohun tí ó le ṣe láì dúró de ìjọba.

Lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, Ààrẹ ní òun kò fi ara mọ.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀