Bandits Proscribed as terrorists: Ìjọba Nàìjíríà kéde àwọn agbébọn gẹ́gẹ́ bíi agbésùnmọ̀mí káàkiri Nàìjíríà

Agbebon

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba Naijiria ti kede awọn agbebọn sọṣẹ gẹgẹ bi asẹrubalu

Kini omaa wa sẹlẹ si wọn bayii?

Ikede yii lo wa ninu iwe atunse ofin 'Gazette" ti ijọba apapọ filede, to fi ofin de ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ lati mase lọwọ ninu iwa awọn asẹrubalu yiiNkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Bello Turji, afurasí bálógun ajínigbé ní Ariwa Naijiria

Gazzette

Oríṣun àwòrán, @Min of Information

Gazette

Oríṣun àwòrán, @Min of Information

Ojọ ru, ọjọ karun un, oṣu kinni, ọdun 2022 ni ijọba gbe iwe ofin kale ti agbẹjọ agba ati minista fun eto idajọ, Abubakar Malami bu ọwọ lu.

Eleyi lo wa lẹyin ti Ile-ẹjọ giga ni ilu Abuja kede awọn agbebọn yii gẹgẹ bi asẹrubalu.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Ninu idajọ ile-ẹjọ naa ni osu kọkanla, odun 2021, Onidajọ Taiwo Taiwo fidi ẹ mulẹ wi pe isesi awọn ẹgbẹ Yan Bindiga and Yan Ta'adda jẹ iwa isẹrubalu.

Ile-isẹ apapọ to n risi ọrọ idajọ ni o gbe ẹjọ yii losi waju onidajọ Taiwo.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Kini atupalẹ iwe atunse ofin 'Gazette' yii sọ?

Ikede náà sọ di mimo wipe àwọn egbe bii Yan Bindiga, ati Yan Ta'adda ati awọn ẹgbẹ miiran to dàbí rẹ ni wọn ti f'ofin de ni gbogbo orileede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Ofin naa fi kun un pe paapaa ju lọ ni ẹkun ariwa Iwo Oorun ati aarin gbungbun ariwa ni orilede Naijiria ni ofin naa de awọn agbebọn serubalu yii.

Eleyi lo wa ni ibamu pẹlu abala kini ati ìkejì ofin isẹrubalu tọdun 2011.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Tani awọn agbebọn yii gan an?

Awon agbebon ti wọn maa n saba fara pamọ si inu igbo ti wọn ti kọtì lati s'ọse ni awọn ilu ati ileto ni ẹkun Ariwa-Iwọ Oorun.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Wọn ti wa darapọ mọ awọn ẹgbẹgun ajinigbe lati gba owo idasilẹ.

Lati bi ọdun mẹwa bayii, o lẹ ni ẹgbẹrun mẹjọ eyan ti wọn ti ku ni awọn ipinlẹ bii Kebbi, Sokoto, Niger ati Zamfara, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ agbaye ton s'akọsilẹ ìkogun jani.

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ

Awọn akọlu wọnyii ni a le lọdi rẹ mọ ede aiyede latẹyinwa laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbegbe ti awọn eeyan kan ya sọtọ lati soko.