Ikoyi collapsed building: Sanwo-Olu ní ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò ṣiṣẹ́ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Lẹyin ti igbimọ oluwadii ile alaja mọkanlelogun to dawo ni Ikoyi niluu Eko jabọ fun un tan, gomina Babajide Sanwo-Olu ni ijọba ṣetan lati ṣiṣẹ lori abọ igbimọ naa.
Sanwo-Olu ṣe ifilọlẹ igbimọ ẹlẹni mẹrin ti kọmiṣọnna iṣẹ aknaṣe, Tayo Bamgbose-Martins jẹ alaga rẹ gẹgẹ bi igbeṣẹ akọkọ lori ati gbe igbesẹ lori abọ igbimọ oluwadii iṣẹlẹ ile to wo ni Ikoyi.
Awọn ọmọ igbimọ mii ni olori awọn oṣiṣẹ, Hakeem Muri-Okunola; Kọmiṣọnna eto idajọ, Moyosore Onigbanjo (SAN) ati akẹgbẹ rẹ ni ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ọgbin, Abisola Olusanya.
- Orí tèmi kọ́ ni àṣà Ibadan yóò ti dàrú- Rashidi Ladoja
- Àwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo
- Àwọn òṣìṣẹ́ RUGIPO ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àìlópin
- Èsì àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni kò fihàn pé ẹnikẹ́ni ló pa á - Kọmiṣọnna ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Bello Turji, afurasí bálógun ajínigbé ní Ariwa Naijiria
- Mọ̀ síi nípa àwọn ọjọ́ tó yàtọ̀ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àkọsílẹ̀ láti ṣẹlẹ̀ lọ́dún yìí
- Erin tẹ obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ pa lọ́jọ́ ọdún
Gomina ipinlẹ Eko ni igbimọ yii yoo jabọ fun igbimọ alaṣẹ ijọba ipinlkẹ Eko ti wọn ba pari iṣẹ wọn tan.
Sanwo-Olu ni igbimọ ẹlẹni mẹrin yii ni di ipari ọsẹ to n bọ lati jabọ lori iṣẹ ti oun gbe le wọn lọwọ.
Ninu ọrọ rẹ, alaga igbimọ oluwadii ohun to ṣe okunfa ile to dawo naa, Toyin Ayinde ṣalaye pe igbimọ naa lọ si ibi ile to wo naa fun ayẹwo.
Bakan naa lo ni igbimọ ọhun tun ṣe amojuto awọn akọṣẹmọṣẹ to n ṣe oriṣiiriṣii ayẹwo lori ile to wa naa.
Ọgbẹni Ayinde fikun ọrọ rẹ pe eeyan mọkanlelaadọrun ni igbimọ naa tun fi ọrọ wa lẹnu wo.
Alaga igbimọ yii tun sọ pe awọn ṣabẹwo si ile oludari ileeṣẹ akọleta Fourscore Heights Limited, oloogbge Olufemi Osibona lati le ri awọn iwe ẹri to le ṣe iranwọ lori iṣẹ iwadii.
Ọgbẹni Ayinde sọ lẹyin ti awọn ti ṣe iwadii fun ọsẹ mẹfa, igbimọ naa ri pe ohun to n ṣokunfa ile wiwo nipinlẹ Eko niiṣe pẹlu aisi iwa ọmọluabi mọ lawujọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2021 ni ile naa dawo lopopona Gerrard ni Ikoyi.
Ọjọ kẹrin oṣu kọkanla yii bakan naa ni Sanwo-Olu gbe igbimọ oluwadii yii dide.












