Àwọn òṣìṣẹ́ RUGIPO ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àìlópin

Awọn oṣiṣẹ RUGIPO

Owó oṣù mẹ́tàlá àti àwọn ajẹmọnu mii ni ìjọba ìpińlẹ̀ Òndó jẹ wọ́n.

Awọn oṣiṣẹ ile-iwe giga Rufus Giwa Polytechnic, Ọwọ, RUPIGO ti bẹẹre ìyanṣẹ́lódì ailopin.

Owo oṣu mẹtala ati awọn ajẹmọnu mii ni ijọba ipinlẹ Ondo jẹ wọn.

Idi yii ni wọn ṣe daṣẹsile ti wọn si sọpe awọn koni pada si ẹnu iṣẹ afiti ijọba ba san owo wọn.

Nibi ifẹhonuhan ti wọn ṣe ni waju ile-iwe naa, awọn oṣiṣẹ gbe ọpọlọpọ Kaadi ajue to ṣakawe oriṣiriṣi ipenija ti wọn dojukọ laatari airi owo oṣu gba.

Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ agba ni Ilẹ-iwe giga RUGIPO, Chris Olowolade ṣalaye pe gbogbo akitiyan wọn lati jẹ ki adari ile-iwe ati ijọba san owo yii lo jasi pabo.

Olowolade sọpẹ idi yi ni awọn fi gunle iyansẹlodi naa.

O juwe igbese adari Ile-iwe naa lati fi ofin de ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi aba ti ko lẹsẹ nilẹ.

Olowolade pe fun iyọnipo awọn adari RUGIPO lori ẹsun pe wọn ngba ọna ti o tọ lati gba oṣiṣẹ eyi to n fa ipalara fun ọrọ aje ile-iwe giga naa.

O fin ku ọrọ rẹ pe awọn koni pada si ẹnu iṣẹ afiti ijọba ati oludari RUGIPO ba san gbogbo owo wọn.

Ti ako ba gbagbe, Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Ogunoye lo parọwa si awọn oṣiṣẹ naa lati fi opin si ifẹhonuhan ati iyansẹlodi ti wọn ṣe ni oṣu karun ọdun 2021.

Amọ, Ọga agba ile-iwe giga RUGIPO, Gani Ogundahunsi fi idaniloju han pe gbogbo awuyewuye ọrọ ọwọ oṣu ni o ma to ni iyanju.Oṣalaye pe awọn alaṣẹ ati adari awon oṣiṣẹ ile-iwe ni wọn ma joko lati yanju gbogbo ọrọ naa.