Pastor Taiwo Odukoya: Ọ̀fọ̀ míìràn tún ṣe Pasítọ̀ Taiwo Odukoya

Iroyin sọ pe arabinrin naa d'ologbe lẹyin ọsẹ diẹ ti iyawo ẹlẹkeeji pasitọ naa ku lẹyin to ti japoro lọwọ aisan jẹjẹrẹ fun ọdun meji

Oríṣun àwòrán, Taiwo odukoya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pasitọ agba ijọ Fountain of Life Bible to wa ni ipinlẹ Eko bi ibeji rẹ Kehide Hassan ṣe tun di oloogbe.

Iroyin sọ pe arabinrin naa d'ologbe lẹyin ọsẹ diẹ ti iyawo ẹlẹkeeji pasitọ naa ku lẹyin to ti japoro lọwọ aisan jẹjẹrẹ fun ọdun meji.

Ọmọ Pasitọ Taiwo Odukoya, Tolu Ijogun lọ sisọ loju eegun ọrọ naa loju opo instagram rẹ lasiko to kọ sibẹ pe oun n selede lẹyin ibatan baba oun to ti duro gẹgẹ bi mama fun awọn ni gbogbo igba ti awọn nilo eniyan bi iya.

Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò

O kọ bayii pe, " Aunti mi "K" ọwọn, ẹni ti o sun mọmi julọ.... ẹyin ni ẹ maa n wa nibẹ fun mi ni ọpọ igba ti mo ba nilo iya mi julọ.

"Ẹ di mi lọwọ mu nigba ti e si ma n gba mi nimọran ... Lakotan ti mo ba sọ pe ayun yin ko ni mumi asọdun ni, Sun-un Re oo Aunti mi ọwọn "

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi