Owo Akure travelogue: Wo ìdí ti Olowo ti ìlú Owo kò ṣe gbudọ̀ jẹ ẹran Ọ̀bọ
Itan sọ pe Olowo to kọkọ jẹ ni ilu Owo ko 'se iṣejọba rẹ ni ibi ti ilu Owo wa gangan lonii.
Laye atijọ, itan ti wọn sọ fun BBC Yoruba ni irinajo lọ si Ilu Owo ni pe Awọn ọba igbaani to jẹ ni ilu Owo ni Aafin wọn si ori oke kan to n jẹ Oke Madẹ.

Oba Gbadegesin Ajibade tun ṣalaye pe ninu itan, ẹranko Ọbọ lo tọna fun Ọlọwọ akọkọ pe ibi ni koo gba.
"Eyi ni wọn fi n ki awọn ọmọ Ọwọ paapaa julọ Ọlọwọ ni oriki pe "Ọlọwọ ko gbọdọ jẹ ẹran ẹdun".


Ki ni ilu Owo ni pọ mọ Ile Ife?
Oba Ojugbelu Olowo akọkọ lo tẹ ilu Owo do ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. BBC Yoruba ṣawari ni ilu Owo pẹ Ojugbelu jẹ ọkan lara awọn ọmọ Oduduwa ati pe ilu Ile Ife ni Ojugbelu ti n bọ to fi tẹdo si ibi ti ilu Owo wa lonii yii.
Itan ki si ilu Ọwọ nipa iṣẹmbaye ilẹ Yoruba. BBC Yoruba n mu eyi wa fun ikọni ati igbadun ẹyin ololufẹ itan ati aṣa Yoruba.

