Deji ìlú Akure pàṣẹ lórí họ́wù-họ́wù ọ̀rọ̀ oyè Iralepo Isinkan nílùú Akure

Deji of Akure

Oríṣun àwòrán, Sola Ilesanmi

Awọn afọbajẹ Isikan mejila ni wọn yan Ọmọọba Olugbenga Ojo, to jẹ ọmọ kẹtala fun Iralepo Isikan to waja, iyẹn Ọba Joseph Olu-Ojo, gẹgẹ bii Iralepo kejidinlogoji.

Lọjọbọ to kọja, labẹ iwoye ati amojuto awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ Guusu Akure.

Ẹwẹ, ko to pe wakati mẹrinlelogun ni Déjì ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi ti juwe igbesẹ ọhun bii awada kẹrikẹri, to si sọ pe eni to ṣe ipo keji nibi idije naa, Henry Adeyeye, ni Iralepo tuntun.

Déjì ilu Akure, to sọrọ latẹnu akọwe iroyin rẹ, Mike Adeyeye, tẹnumọ pe oye Iralepo ni ile ẹjọ to ga julọ nilẹ yi ti ṣe apejuwe rẹ bii olori agbeegbe kan nilu Akure ti kii ṣe Ọba rara.

O ni, Oloye giga Henry Adeyeye lo ti ṣaaju gba iwe iyansipo gẹgẹ bii Oloye Iralepo lati ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ọdun yii, to si jẹ pe lakoko to lọ lati ṣe ipade pẹlu awọn ẹbi ni wọn wi fun pe idibo yan ọba tuntun ni awọn fẹẹ ṣe, leyi ti wọn si kọ iye ibo to wu won fun.

Gbogbo igbiyanju akọroyin BBC Yoruba lati ba Henry Adeyeye sọrọ lo ja si pabo lẹyin to kọ lati gbe ipe lori ẹrọ ilewọ rẹ, ti ko si fesi si awọn atẹjiṣẹ taa fi ranṣẹ si ori ila naa.

Amọ ṣa, Ọmọọba Olugbenga Ojo sọ fun ile iṣẹ iroyin BBC Yoruba pe ootọ ni pe ile ẹjọ fi idi rẹ mulẹ pe Déjì ni ọba alaye ti ipo rẹ ga julọ nilu Akure, amọ eyi ko sọ pe Iralepo kii ṣe ọba.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

O ṣalaye siwaju si pe iyansipo oun lo tẹle gbogbo alakalẹ ofin ati ilana ibilẹ, leyi to jẹ ki o ya oun lẹnu pe ẹni ti wọn jọ du oye to to si ni oun faramọ abajade iyansipo ọhun lẹyin to wa ni ipo keji nibi idibo iyannisipo naa, yoo lọ gba oye lọdọ Deji.

Akọwe ijọba ibilẹ guusu Akure, Gbenga Fasua to boju to eto iyansipo naa wipe gbogbo ohun ti wọn ṣe ni ko si eyikeyi ninu rẹ to tako ofin.

O fikun pe atupalẹ idajọ ile ẹjọ fihan pe ipo Iralepo ti Isinkan ni ofin ṣi ri gẹgẹ bi ipo ọba ni ibamu pelu ofin ijọba ibilẹ ati ti ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Àwọn abirùn ọmọ tí òbí wọn tì mọ́lé ni mo lọ ń kó jáde láti máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ iléèwè - Sekinat Ahmed