NCC Alerts to Telcoms: Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa bí "Flubot Malware" ṣe lè kọlu fóònù yín lójijì?

Foonu alagbeka

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọsẹ to kọja ni ajọ to n mojuto awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, NCC, ke si awọn araalu lati ṣọra fun kokoro ijamba Flubot Malware to le ṣe foonu wọn.

Diẹ lara awọn nkan to yẹ lati mọ nipa Flubot:

1. Ẹrọ ibanisọrọ Android ni Flubot ma n doju kọ

Kokoro Flubot ma n fi ara rẹ han bi awọn Ápp banki, lati le gba akọsilẹ nipa awọn App miran to wa lori foonu rẹ. Afojusun rẹ si ni lati gba akọsilẹ nipa rẹ, kaadi ATM rẹ, ati 'password' to fi n lo App banki lori foonu.

2. Atẹjiṣẹ SMS ni wọn fi n pin Flubot

Flubot ma n wọ ori foonu nipasẹ atẹjiṣẹ, o si le ṣe amí awọn atẹjiṣẹ to ba wọle, o le pe awọn nọmba ori foonu rẹ, o le ka tabi kọ atẹjiṣl, o si tun le ko awọn nọmba ti o ni sori foonu rẹ lọ si ile agbara rẹ.

3. O le gba ori foonu rẹ ṣe ijamba fun ẹlomiran

To ba ti wọ ori foonu rẹ nipasẹ atẹjiṣẹ, yoo fi iru atẹjiṣẹ bẹẹ ranṣẹ si awọn nọmba to wa lori foonu rẹ pe ki awọn naa download ayederu app naa.

4. Awọn kokoro miran le gba ibẹ wọle

Ti Flubot ba wọ ori foonu kan, o le yọri si pipanu owo. Bakan naa ni 'malware' yii yoo ṣi ọna silẹ fun awọn to wa ni idi bo ṣe wọle lati tun fi awọn iru malware mii ranṣẹ sori foonu naa.

Awọn nkan miran to tun ṣe koko nipa Flubot Malware

"Flubot" yìí máa n farahàn lórí fóònù "Android" rẹ gẹ́gẹ́ bi àwọn abánifẹ̀rù ránṣẹ́ DHL, FEDEX, Correos tàbi èròjà Chrome tí ó ń lò lórí fóònù rẹ̀, èyí ni yóò si fi gba ẹ̀lòmííràn láàyè sórí fóònù rẹ láti mọ bi ǹkan ṣe ń lọ.

Nínú àtẹjáde tí olùdarí ọ̀rọ̀ tó kan ará ìlú ní NCC Dr Ikechukwu Adinde fọ́wọ́ si ló ti ṣàlàyé pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà, irú àwọn kòkòrò yìí wà láti ba àwọn ǹkan jẹ́ lórí fóònù, tàbí láti ni ànfàní si lílo fóònù náà.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

NCC ní gẹ́gẹ́ bi nǹkan ti àwọn gba láti ọ̀dọ̀ àjọ tó n ri si ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ẹ̀rọ ayára bí àsá ni Nàìjíríà (ngCERT) ló ṣàlàyé pé, Android ni Flubot n koju, ti yóò si wá bi ẹni pe o ni láti gba áàpù ààbò sórí ẹ̀rọ ìpè rẹ.

ngCERT fi kun un pé, nígbà mííràn kòkòrò yìí a wá bíi áàpù bánkì rẹ̀ láti tàn ọ lọ sórí ojú òpó òfégè, tí wọn yóò sì jí àwọn dátà rẹ lójúnà láti pada jí owó tó wà nínú àpò ìkówópamọ rẹ̀ ni Bánki.

Flubot yìí bákan náà tún máà n tàn ká nípa àtẹ̀jíṣẹ (sms) tí o si le rí àwọn nǹkan mííràn tó bá ń wọlé sí orí fóònù rẹ̀, ká àtẹ̀jísẹ́ rẹ bákan náà ni o le fi àwọn nọ́mbà orí fóònù rẹ ránṣẹ́ si olú ilé wọ́n.

Malware tuntun yìí a maa sọ èròjà ààbò orí fóònù rẹ di aláìlágbára ti o si le fa kí ènìyàn pàdánù owó, bákan náà ló ni ilékùn mííràn tí yóò gba ọ̀nà ẹ̀yìn ṣí láti mú àwọn ẹni ibi yìí fi orúkọ tàbi nǹkan ìní rẹ hùwà ọdaràn tàbí kí o tún kó àwọn kòkòrò míírà sórí fóònù rẹ.

Kíni àwọn nǹkan tí o le ṣe láti dènà Flubot lórí fóònù rẹ̀?

1. Má tẹ ojú ìlà (link) kankan ti wọ́n ba fi àtẹjíṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ, bákan náà si ni kí o má gba áàpù tábi gba aapu ìdáàbòbo kankan sí orí fóònù rẹ.

2. Lo àwọn áàpù tó ń dènà kòkòrò tàbi tí yóò ta ọ lólobó ti nǹkan ti ko dara bá wà lórí fóònù rẹ (Antivirus).

3. Ṣe àyẹ̀wò kí o tó tẹ ojú ìlà tàbí gba áàpù kan si orí fóònù rẹ.

4. Gbé àgádágodo tó lágbára sí ẹnú ọ̀nà àwọn áàpù tí ò ń lò, kí ó sì tún fí áàpù oní ọ̀nà méjì (2FA) tí o bá fẹ́ lo fóònù.

5. Máa dáàbò bo iṣẹ́ rẹ lójoojúmọ ati àwọn dáta rẹ kí o ma baa sọnú.

6. Ti àwọn nǹkan wọ̀nyìí bá bá ọ wí, ó ṣe pàtàkì kí o dá fóònù rẹ padà sí bi o ṣe ràá lóní wàrànsesà, èyí yóò yọ gbogbo kòkòrò tí kò tọ́ to bá ti wà lórí fóònù rẹ kúrò.

7. Má ṣe àdápàdà àwọn àápù tí ò ń lọ tẹ́lẹ̀, yálà tun wọn gbà sí ori fóònù rẹ, o le ké si ngCERT lójú òpó [email protected] fún ìrànwọ́.

8. Bákan náà o nílò láti ṣe àyípadà sí 'Password" rẹ pàápàá jùlọ lórí gbogbo àwọn áàpù tí òun lò àti gbogbo àtẹ̀jíṣẹ́ Banki rẹ.

9. Bí o bá wá rò pé ẹni ti ko tọ ti ni àṣẹ si fóònù rẹ, tètè kan sí Banki ré lati ṣe àtúnṣe.