Yollywood: Oṣù díẹ̀ ṣẹ́yìn lé fún mi nítorí bí ojú ìyá mi tó fọ́ ṣe tún le koko - Funmi Awelewa

Funmi Awelewa

Oríṣun àwòrán, funmi awelewa

Gbajagbaja oṣerebinrin, Funmi Awelewa, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Morili kede pe nkan le koko fun oun ni osẹ diẹ sẹyin.

Eyi ko ṣẹyin aisan kan to n ṣe iya rẹ.

Ninu ọrọ to kọ si ori Instagram rẹ, o ni ọrọ aisan naa de ibi kan to jẹ pe ọkan oun daamu pupọ, ti oun ko ti ẹ le sọ pe ipo bayii ni ọkan oun wa.

Nibẹ lo si tun fi fidio kan si, to ṣafihan bi ẹjẹ ṣe n jade ninu oju iya rẹ.

O ni "ki eeyan ri iya rẹ ko ma a la irora nla kọja le da ọkan eeyan rú. Iya to ti fọ loju tẹlẹ lati ọpọlọpọ ọ̀un sẹyin.

"Bi mo ṣe n ri ninu inira bami ni ọkan jẹ pupọ, o si ni ipa lara gbogbo nkan to yi mi ka."

Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ

Arabinrin Awelewa sọ pe ọrọ aisan iya naa ni ipa lara iṣẹ oun gẹgẹ bi oṣere, nitori pe lati inu osẹ Keje, ọdun 2021 ni oun ko ti lọ si ibi iṣẹ kankan mọ, ki oun le raaye mojuto iya naa.

Bakan naa lo sọ pe o tun ṣe akoba fun okoowo oun, nitori pe oun n lọ lati ileewosan si ileewosan miran ni.

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

"Ọpọlọpọ iwe ipe sibi ayẹyẹ ni mo kọ̀, koda awọn akẹẹgbẹ mi kan ro pe mi o fẹ ẹ ba wọn ṣe pọ ni, tabi boya mo n gberaga lai mọ pe lai mọ pe mo ni nkan ti mo n ba a finra, to jẹ ilera iya mi."

Awelewa sọ pe idunnu wo ni oun fẹ ẹ ni, nigba ti iya oun wa ninu inira.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

O ni ṣe ti owo ti oun n na lojoojumọ ni ki oun sọ ni, tabi oogun o ni wakati meji-meji.

O sọ pe ṣugbọn oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe iya naa jade ninu aisan laaye.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Amọ o, Morili sọ pe nkan ẹyọkan ṣoṣo ti oun n beere lọwọ Ọlọrun ni pe ko fun iya oun ni anfaani lati pada fi oju rẹ riran, bi ko tiẹ ju iṣẹju marun-un lọ lati ri nkan ti ọmọ rẹ ti dà.

Àkọlé fídíò, New year prayers: Gbọgbọọgbọ lọwọ́ n yọ ju orí, gbogbo wa laó yọ ju ọ̀tá wa lọ