Ọwọ́ ọmọ ogun Naijiria tẹ obìrin tó ń ta igbó fún Boko Haram ní Borno

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army
Ọwọ ọmọ ogun Naijiria to ti tẹ obinrin kan, Hauwa Abulazeez, lori ẹsun pe oun lo maa n ko oogun oloro fun awọn ọmọ ogun Boko Haram ni iha Ariwa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun, ẹka ti Joint Task Force, Operation Hadin Kai, Sanni Uba, sọ pe ijọba ibilẹ Askira Uba, nipinlẹ Borno ni ọwọ ti tẹ afurasi naa.
Ọgagun Uba sọ pe obinrin naa lo n ko egboogi igbo fun Boko Haram ni Askira Uba, Rumirgo, Gwahi, Wamdiyo, Uvu ati Gaya.
Uba sọ pe awọn ọmọ ogun labẹ akoso Operation Desert Sanity V "tun ti ṣe aṣeyọri mii lati rẹyin awọn agbesunmọmi ni iha ariwa.
"Lẹyin ti awọn kan sin wa nigbẹrẹ ipakọ lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kinni, ọdun 2026, a fi ṣikun ofin mu Hauwa Abulazeez, ẹni ọdun marunlelọgọta, ni ijọba ibilẹ Askira Uba, nipinlẹ Borno.
"Afurasi naa ni a gbọ pe o n ta egboogi igbo fun awọn agbesunmọmi Boko Haram ni Askira Uba, Rumirgo, Gwahi, Wamdiyo, Uvu ati Gaya, to tun jẹ ọkan gboogi lara awọn to n ta oogun oloro lagbegbe ọhun."
Iwadii fi han pe ijọba ibilẹ Sarti Baruwa to wa nipinlẹ Taraba obinrin naa ti maa n ra oogun oloro ọhun ko to maa pin kaakiri fun awọn onibara rẹ.
Nigba ti ọwọ tẹ afurasi naa, idi igbo mẹrinla ti iwọn rẹ to 30kg ni wọn ka mọ lọwọ.
Uba pari ọrọ rẹ pe afurasi ọhun ti wa lakata awọn bayii fun iwadii ni kikun.
O fi kun pe iṣẹ ti n lọ lọwọ lati mu awọn ẹmẹwa rẹ.















