Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì gbẹ̀mí èèyàn méje ní Indonesia, èèyàn 80 míì di àwátì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan meje lo ti dagbare faye, nigba ti ọgọrin mii tun di awati lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riru to waye ni Indonesia.
Agbegbe West Bandung, to wa ni guusu ila oorun ilu Jakata, to jẹ olu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lẹyin ti ojo rọ fun ọpọ ọjọ.
Awọn alaṣẹ sọ pe o le ni ile ọgbọn to dawo lẹyin ti ilẹ gbe agbagbe ti awọn eeyan n gbe mi, eyii to ṣakoba fun awọn eeyan nibẹ.
Ijọba ti wa kede pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ omiyale, ilẹ riri ati oju ọjọ ti ko fararọ waye lagbegbe naa bayii.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, nnkan bii aago meji oru oni ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Lọwọ yii, wọn ti ri eeyan mẹrinlelogun doola lai farapa rara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abdul Muhari, to jẹ agbẹnusọ fun ajọ adoola ẹmi to n bojuto iṣelẹ naa, National Search Agency,NSA, ṣe sọ.
Awọn aworan ti awọn eeyan agbegbe naa pin lori ayelujara ṣafihan bi awọn ile kan ṣe wo lori ara wọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ bayii yoo waye ni Indonesia.
Loṣu Kinni ọdun to kọja, eeyan to le ni ogun ni agbara omi gbe lọ ni aringbungbun Java.
Ninu oṣu Kejila, ọdun 2025 ni agbara omi ati ilẹ riri tun kọlu erekusu Sumatra nibi ti ẹgbẹrun kan ati igba eeyan ti jade laye.
Ajọ adoola ẹmi sọ lasiko naa pe ẹgbẹrun meje eeyan lo farapa ninu iṣẹlẹ ọhun.













