Kí ni ìgbìmọ̀ àlááfìà tí Trump ń pé àwọn orílẹ̀èdè sí pẹ̀lú àwọn tó ti darapọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede America, Donald Trump ti bẹrẹ si i pe awọn orilẹede agbaye lati darapọ mọ agbekalẹ kan to n ṣeto rẹ, eyi to ni o wa fun ki alaafia le jọba kari aye.
Agbekalẹ alaafia naa ni Trump pe ni Board of Peace initiative, ohun to si ni o wa fun ni lati yanju aawọ to n ṣẹlẹ kaakiri agbaye.
Amọ awọn awoye ti n sọ pe eto ti Trump n ṣagbatẹru rẹ yii le mu ewu dani fun Iṣọkan Agbaye.
Bakan naa ni ero awon orilẹede paapaa ko jọ ara wọn nipa ọwọ iranwọ alaafia ti Aarẹ Trump loun n na yii.
Bi awọn orilẹede to jẹ alajọṣe pẹlu America lati igba pipẹ ṣe n gba aba alaafia naa wọle ni wọn n tun n ṣọra, awọn kan ko si tilẹ gba lati ba Trump da ohunkohun pọ.
Kí ni igbimọ alaafia Trump gan-an?
Ọrọ igbimọ alaafia ti Aarẹ Trump gbe kalẹ yii kọkọ waye loṣu Kẹsan-an ọdun to kọja, nigba to ni oun fẹ fopin si ogun Gaza.
Lẹyin igba naa ni Trump tun kede pe eto alaafia naa yoo kọja Gaza, yoo kari aye ni.
Aarẹ Donald Trump naa ni yoo jẹ alaga igbimọ yii, iṣẹ wọn bo ṣe kede naa si ni lati ri I pe aigbọra ẹni ye ati wahala yanju kari aye.
Awọn orilẹede to ba darapọ yoo maa jẹ ọmọ ẹgbẹ fun ọdun mẹta pere, afi bi ọkọọkan wọn ba san biliọnu kan dọla ($1 billion) ti wọn yoo maa lo ninu igbimọ naa, ni wọn yoo too le di ọmọ ẹgbẹ patapata.
Lara awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ naa bi ijọba America ṣe kede ni Akọwe ijọba America; Marco Rubio, amugbalẹgbẹẹ pataki fun Trump; Steve Witkoff, Olootu ijọba Gẹẹsi tẹlẹ; Tony Blair ati Jared Kushner to jẹ àna Aarẹ Donald Trump.
Awọn orilẹede wo lo ti gba lati darapọ?
Bo tilẹ jẹ pe ero awọn orilẹede ṣọtọọtọ nipa didara pọ mọ agbekalẹ Aarẹ Trump yii, awọn kan ti gba lati di ọmọ igbimọ naa.
Ninu orilẹede aadọta ti iroyin sọ pe wọn ti fi iwe pe lati darapọ, o ti to marundinlogoji (35) ti wọn ni awọn yoo di ara igbimọ alaafia naa.
Lara awọn ti wọn ti gba ni
Middle East & North Africa
Israel
Saudi Arabia
United Arab Emirates
Bahrain
Jordan
Qatar
Egypt
Morocco
Europe
Turkey
Hungary
Kosovo
Armenia
Azerbaijan
Belarus
Asia
Pakistan
Indonesia
Uzbekistan
Kazakhstan
Vietnam
Latin America
Paraguay
Lalẹ Ọjọru ọsẹ yii ni Trump sọ pe Russia naa ti gba lati darapọ, bo tilẹ jẹ pe Vladimir Putin to jẹ Aarẹ Russia dahun nigba naa pe oun ṣi n yẹ aba naa wo.
Bakan naa ni China ti oun ati America ki I gbọra wọn ye naa ṣi n ṣọra lori igbimọ alaafia Trump yii.
Awọn orilẹede wo lo kọ lati gba, atawọn ti ko ti i gba?
Lara awọn orilẹede to kọ lati gba ipe Trump ni Norway ati Sweden, nigba ti Italy ṣi n sọ pe didarapọ yoo ko ba ofin orilẹede awọn.
Bakan naa ni iroyin n sọ pe France paapaa ko fẹ gba ipe lati darapọ yii.
Canada ni tiẹ ni oun faramọ ilana yii, ṣugbọn oun n ṣiṣẹ lorii rẹ lọwọ.
Awọn ọrẹ America bii Britain, Germany ati Japan naa ko ti I kede ni gbangba boya won yoo darapọ tabi bẹẹ kọ.
Ukraine ni awọn awoye ọdọ oun ṣi n gbe e yẹwo lọwọ, ṣugbọn Aarẹ Volodymyr Zelenskiy ti ni o nira foun lati wa ninu igbimọ kan naa pẹlu Russia lẹyin ọdun mẹrin tawọn fi jọ jagun.













