Ìfẹ̀hónúhàn bẹ́ sílẹ̀ l'Amẹrika lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè ICE yìnbọn pa aráàlú

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn oṣiṣẹ aṣobode ilẹ Amẹrika, Customs Enforcement (ICE), ti gbẹmi ọkunrin kan niluu Minneapolis, iṣẹlẹ naa si ti yọri si ibinu araalu.
Ọpọ araalu lo tu jade lai wo ti otutu to wa lode lati fẹhonuhna lẹyin iku Alex Pretti, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
Oniruru fidio ti awọn eeyan to wa nibẹ ya ṣafihan ohun to ṣẹlẹ laarin awọn agbofinro naa ati Pretti.
Ijọba ipinlẹ ti iṣelẹ naa ti waye ati ileeṣe agbofinro ijọba apapọ ti gbiynaju lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni pato amọ alaye wọn tako ara wọn.
Iṣẹlẹ laabi yii lo n waye laarin ọsẹ mẹta pere ti agbofinro ICE yinbọn pa Renee Good ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ni Minneapolis yii kan naa.
Ẹwẹ, ijọba Trump ti juwe iṣẹlẹ naa pe oloogbe lo kọkọ kọju ija si awọn agofinro ọhun.
Ijọba ni ṣe ni oloogbe naa koju awọn agbofinro ọhun pẹlu ibọn ilewọ lọwọ rẹ ati pe lẹyin ti gbogbo gbiyanju lati gba ibọn naa lọwọ rẹ ja si pabo ni wọn to ṣina ibọn fun.
Amọ awọn fidio ori ayelujara tako nnkan ti ijọba sọ pe o ba awọn agbofinro naa lo agidi.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Dipo eyii, awọn fidio ori ayelujara ṣafihan bi wọn ṣe yin tajutaju alata si ti wọn si fi agidi mu mọlẹ ki ibọn to dun.
Ijọba Trump ti juwe oloogbe naa gẹgẹ bii agbesunmọmi abẹle, amọ gomina ipinlẹ Minnesota, Tim Walz ti juwe ọrọ ijọba bii irọ nla.
Lalẹ ọjọ Abamẹta ti iṣẹlẹ naa waye, ọpọ eeyan lo ṣedaro oloogbe naa ni Minneapolis nipa titan abẹla atawọn ina mii.
Nigba ti yoo di ọsan lawọn eeyan tu sita lati fẹhonuhan lodi si awọn oṣiṣe Customs Enforcement (ICE) to ṣokunfa iku ọkunrin ọhun.
Yatọ si Minneapolis, awọn eeyan tun ti ṣe iwọde ni New York, Chicago, Los Angeles ati San Francisco.















