Buhari interview: Ààrẹ Buhari ní ìjọba òun kò lè fi Nnamdi Kanu láì ṣàlàyé ara rẹ̀ nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Aarẹ orilẹ-ede Naijriia, Muhammadu Buhari sọ pe oun ko reti ki awọn ọmọ Naijiria yin oun lẹyin to ba pari saa iṣejọba rẹ.
Iwe iroyin Cable jabọ pe aarẹ sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwanilẹnuwo to sẹ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan NTA ni Ọjọbọ.
Buhari sọ pe gbogbo nkan to wa ni ikapa oun ni oun ṣe fun orilẹ-ede Naijiria lasiko ti oun fi jẹ aarẹ.
- Àwa náà ṣetán láti ma gbé oúnjẹ àti máàlù wà silẹ Igbo- Oloúnjẹ̀ ilẹ̀ Àríwá
- Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko
- Àrà mérìírí! Ìbejí tí a bí ní ọdun 2021 àti 2022 pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dògún láàrin wọn
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti wẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún àti òṣìṣẹ́ márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ Dowen College mọ́
- Ojú máa ń tì mí láti rẹ́rìn ín nítorí irú eyín ẹnu mi ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mo padà dí arìnrìnoge- Omotola Ekundayo
- Ènìyàn mọ́kàndínlógún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Kano
- Oṣù díẹ̀ ṣẹ́yìn lé fún mi nítorí bí ojú ìyá mi tó fọ́ ṣe tún le koko - Funmi Awelewa
O ni ireti oun ni pe nigba ti iṣejọba oun ba pari ni ọdun 2023, awọn ọmọ orilẹ-ede yoo ri i pe oun ṣe nkan ti agbara oun ka.
Aarẹ ni "oriṣiriṣi ọna ni mo ti gba sin orilẹ-ede yii. Mo ti sẹ gomina, minisita, mo si tun ti ṣe aarẹ fun igba meji.
Ki lo tun ku ti mo fẹ ẹ ṣe fun orilẹ-ede yii ti mi o ti i sẹ?
"Mo sẹ iwọn ti mo le ṣe. Nkan ẹyọkan ti mo n reti nigba ti mo ba kuro ni ipo aarẹ ni pe ki awọn ọmọ Naijiria sọ̀ pe ọkunrin yii ṣe iwọn to le ṣe fun Naijiria,'' Buhari lo sọ bẹẹ.
Aarẹ Naijiria tun sọ pe ijọba oun ko le da olori ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Igbo silẹ,IPOB, Nnamdi kanu silẹ.
Buhari ṣalaye pe Kanu gbọdọ ṣalaye ara rẹ nile ẹjọ pe oun o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Buhari ni ''awọn ọmọ Naijiria ko mọ pe n kii dasi ọrọ ile ẹjọ.
Fun gbogbo awọn ti wọn n sọ pe ki a fi Kanu silẹ, a ko le fi i silẹ bayẹn.
A ṣi le lo oṣeleu lati yanju ọrọ naa tawọn ti ọrọ kan ba huwa daadaa ṣugbọn ẹnikan ko le lọ joko si oke okun ki o si maa da Naijiria ru lati ibẹ.''












