Kano Accident: Ènìyàn mọ́kàndínlógún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Kano

Ijamba Oko
Àkọlé àwòrán, Àwòrán ibi ìjàmbá

Ènìyàn mọ́kàndínlógún ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn tí àwọn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n mìíràn sì farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní òpópónà Kano sí Zaria.

Ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ló wáyé ni agbègbè ilé ẹ̀kọ́ Horas Law School ní Bagauda lẹ́yìn tí àwọn ọkọ̀ méjì kan ṣàkọlù sí ara wọn kí wọ́n tó gbiná.

Agbẹnusọ àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Labaran sọ fún BBC pé eré àsápajúdé ló ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ́ náà.

Ó ní àwọn ti ṣàgbékalẹ̀ àwọn òkú tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ náà fún àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, tí àwọn tó farapa sì ti wà ní ilé ìwòsàn gbogbogboò ìjọba ìbílẹ̀ Kura fún ìtọ́jú.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Labaran ṣàlàyé wí pé àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ri dájú pé gbogbo àwọn awakọ̀ fi ẹ̀rọ aṣàmójútó eré sísá sínú ọkọ̀ wọn lójúnà à ti lè mú àdínkù bá ìjàmbá ojú pópó.

Bákan náà ló ní àwọn ti n ṣe ìpolongo lọ́ sí àwọn pápákọ̀ káàkiri tó fi mọ́ ọ̀dọ̀ àwọn olórí ẹsin gbogbo lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Ìjàmbá ọkọ̀ ló sába máa ń wáyé ní àwọn òpópónà orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, tí àwọn ọ̀nà tí kò dára, ìwàkuwà àti eré àsápajúdé máa ń sábà ṣokùnfà wọn.