Kwara brutal Flogging: Bàbá ọ̀kan lára akẹ́kọ̀ọ́ ilé Keu ní òun lọ́wọ́ sí ìjìyà àlùbami

Bayii ni wọn ṣe lu awọn akẹkọọ naa

Oríṣun àwòrán, Screenshot/facebook/fresh insight tv

Baba ọkan ninu awọn akẹkọọ ile Keu ti wọn lu bi ẹran nilu Ilorin ti sọrọ pe oun lo fun awọn alaṣẹ ile Keu naa lati lu ọmọ oun bẹẹ.

Ọjọ Satide ni fidio kan jade si ori ayelujara, eyi to ṣafihan mẹrin lara awọn ọmọkunrin ile Keu naa, Misbaudeen Al Islamiy Arabic school, to wa ni agbegbe Ganmo, nijọba ibilẹ Ifelodun, nipinlẹ Kwara, to n lu awọn akẹẹgbẹ wọn mii ni ẹyọkọọkan.

Ninu fidio naa lati ri i pe awọn akẹkọọ ti wọn n lu, n kunlẹ ni ẹyọ kọọkan, ti akẹkọọ mẹrin mii to jẹ ọkunrin si n fi ẹgba lu wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni ohùn awọn olukọ n jade ninu fidio naa pe, "ẹ lu daadaa. Ẹ ma a ṣaanu ẹ".

Ẹsun ti wọn fi kan awọn akẹkọọ naa ni pe wọn lọ si ile itura kan lati sẹ ayẹyẹ ọjọ ibi akẹẹgbẹ wọn kan, ti oun naa jẹ akẹkọọ ile Keu naa.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Wọn lu ọmọbinrin naa titi Hijab to wọ fi jabọ.

Bakan naa ni wọn ṣe lu awọn akẹkọọkunrin naa, debi i pe ọkan lara wọn ṣubu, to dojubolẹ ki wọn o to o fi silẹ.

O kere tan, ẹgba to to aadọta lo bọ si ara ẹni kọọkan wọn.

Yunus Olanrewaju to jẹ baba ọmọbinrin to wa lara awọn ti wọn na, sọ fun BBC pe, o ti le ni ogun ọdun ti oun ti mọ ile Keu naa, ọmọ oun mẹjọ lo si ti kọ Keu yege nibẹ.

O ṣalaye pe oun ni o n fun ile Keu ni aṣẹ lati fi gbogbo iya to ba yẹ jẹ ọmọbinrin naa, lẹyin to ri i ninu fidio kan pẹlu awọn ọmọkunrin ti wọn n mu ọti nibi ariya kan.

Inu ọgba ile Keu naa

O ni ọmọ oun ọkunrin to n gbe nilu Eko lo fi fidio to ṣafihan ọmọ oun obinrin laarin awọn ọmọkunrin, ti wọn n mu ọti nile itura, ransṣẹ si oun.

"Mo fi ọrọ naa to awọn alaṣẹ ile Keu naa leti, mo si sọ fun wọn lati fi iya to tọ jẹ ẹ. Koda, mo sọ fun wọn pe mo gbọdọ wa nibi ti wọn ba ti n ba a wi."

Awọn alaṣẹ ile Keu naa sọ pe awọn ba wọn wi gẹgẹ bi ilana to wa ninu Kuraani, ati aṣẹ awọn obi wọn.

Ṣugbọn ṣa, ijọba ipinlẹ Kwara ti da ọga ile Keu naa duro, awọn akẹkọọ naa si ti n gba itọju nileewosan.

Awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Kwara ti lọ si ile Keu naa fun iwadii, wọn si ti da ọga ibẹ duro
Àkọlé àwòrán, Awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Kwara ti lọ si ile Keu naa fun iwadii, wọn si ti da ọga ibẹ duro fun igba diẹ