Kwara Hijab crisis: ìgbìmọ̀ olùwádìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ohun tó ṣokùnfà wàhálà hìjáàbù

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wọ hìjáàbù

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wọ hìjáàbù

Ìgbìmọ̀ olùwádìí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àgbékalẹ̀ láti ṣèwádìí ohun tó ṣokùnfà làásìgbò tó bẹ́ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ girama Oyun Baptist High School, Ijagbo, ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ní ìlú Ilorin, olú ìpínlẹ̀ Kwara.

Níbi ìjókòó wọn àkọ́kọ́, alága ìgbìmọ̀ náà, Dókìtà Shehu Omoniyi ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ náà kìí ṣe láti dúnkokò mọ́ ẹnikẹ́ni bíkòṣe láti fìdí ohun tí ó wáyé níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ gan.

Omoniyi tẹmpẹlẹ mọ pé kókó ohun tí àwọn yóò ṣiṣẹ́ lé lórí ni láti mọ kí ló ṣẹlẹ̀, báwo ni ọ̀rọ̀ lílo ìjáàbùṣe di yánpọnyánrin àti láti ṣe àgbékalẹ̀ ìmọ̀ràn tó yẹ fún ìjọba kí irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ má bá a lè wáyé lọ́jọ́ iwájú.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀, kí wọ́n sì sọ òótọ́ lójúnà àti lè gbé ìmọ̀ràn tó da kalẹ̀ fún ìjọba.

Ó fi kun pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni àwọn yóò fi ṣe iṣẹ́ tí tọ̀tún tòsì yóò sì dunnú sí èsì àbájáde ìwádìí àwọn.

Bẹ́ẹ̀ náà ló pé fún fífi àyè gba ara ẹni pàápàá tó bá ti jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, kí ìbágbápọ̀ àláfíà le wà ní àárín ìlú.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab

Olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Oyun Baptist High School, Ijagbo ní ọjọ́rú ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kìnní, àti ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kẹta, oṣù kejì ọdún 2022, olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà, Francis Lambe ṣàlàyé bií iṣú ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Lambe ní ọ̀rọ̀ náà bá ẹ̀yìn yọ nígbà tí àwọn Kìrìsìtẹ́nì ìlú Ijagbo fárígá wí pé àwọn kò ní gbà kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mùsùlùmí lo hìjáàbù ní ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́.

Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ní ilé ẹ̀kọ́ náà àti pé ipa tí ìjọ Onítẹ̀bọmi ń kó ni láti fún ìjọba lámọ̀ràn lórí ẹni tí yóò bá jẹ olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà.

Bákan náà ló ní gbogbo ìpàdé àti ìjíròrò tí àwọn ṣe pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ni kò so eso rere.

Lambe wa rọ ìjọba láti pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kìrìsìtẹ́nì, CAN àti àwọn olórí ẹlẹ́sìn mùsùlùmí fún ìjíròrò láti lè jẹ́ kí wọ́n mọ gbogbo òfin ìlànà ìjọba lórí ètò ẹ̀kọ́.

Ó ní ó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn wà ní títì pa pẹ̀lú ìdánwò WAEC ṣe ń súnmọ́ etílé.

Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀?

Yàtọ̀ sí Dókítà Shehu Omoniyi tó jẹ́ alága, Akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ijagbo, Emmanuel Adebayo Fatola náà jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ alága.

Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ni Pásítọ̀ Modupe Oreyemi Agboola, Ọ̀mọ̀wé Saudat Baki, Alhaji Ibrahim Zubair Danmaigoro, Ẹni ọ̀wọ̀ Timothy Akangbe, tí Onídàjọ́ Ishola Olofere sì jẹ́ akọ̀wé.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ọrọ Hijaabu wiwọ ni awọn ileẹkọ ijọba nipinlẹ Kwara tun ti n da wahala silẹ pada.

Lọjọbọ, ija waye laarin awọn obi ati akẹkọọ kan ti wọn se iwọde lọ si ileẹkọ Girama Oyun Baptist Secondary School ni Ijagbo lori pe awọn alasẹ ile ẹkọ naa ko jẹ ki awọn ọmọ wọn to wọ Hijaabu wọ kilaasi.

Ọrọ yi lo di wahala ti ikọlu si waye laarin awọn ọdọ musulumi ati Kristẹni to doju ija kọ ara wọn.

Ni bayi, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ki wọn ti ileẹkọ naa pa titi ti alaafiayoo fi pada sibẹ.

Ijọba Kwara to gbẹnu Kọmisana feto ẹkọ Hajia Sa'adatu Modibo Kawu sọrọ sọ pe awọn bẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Ijagbo yi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kini Komiṣọnna sọ lori iṣẹlẹ yii?

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna fi sita lỌjọbọ, ijọba sọ pe awọn lawọn ni ile ẹkọ Oyun Baptist Secondary School tori naa nkan to sẹlẹ yi awọn ko faramọ rara.

"Ijọba Kwara fi tọkantọkan koro oju si idẹyẹsi ẹnikankan paap awọn ọmọde nitori ẹsin.A ko ni faramọ iwa yi ni eyikeyi ileesẹ ijọba eleyi ti o ba jẹ ti ijọba''.

Kọmiṣọnna naa tẹsiwaju pe ''Pẹlu bi ijọba ati awọn ajọ rẹ se n jiroro pẹlu awọn olori ẹsin mejeeji, a ti wa pasẹ bayi pe ki wọn ti ile ẹkọ naa pa tti ti ọrọ yi yoo fi lojutu''

''A rọ awọn agbofinro lati se iwadii lori ọrọ yi ki wọn si mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu isẹlẹ yi kawọn eeyan baa le kọgbọn lara rẹ.Ijọba n beere fun alaafia nitori wahala kii so eso rere''.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Ki lawọn ọlọpaa sọ?

Ileesẹ ọlọpaa fi ọrọ sita ninu atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ wọn Ajayi Okasanmi pe awọn fẹ fi da araalu Kwara loju pe alaafia ti pada si agbegbe naa.

O ni ''ikọ kogberegbe ati awọn ọlọpaa to wa nilẹ ni ijagbo ti da alaafia pada si agbegbe naa ti wọn si duro digbi la ti ri pe wahala kankan ko waye nibẹ''

Agbofinro se alaye pe ọrọ hijaabu lo da wahala silẹ laarin awọn musulumi ati Kristẹni ti o ti n waye ti pẹ nipinlẹ Kwara.

''Eleyi to kan wa ni ọrọ wahala to bẹ silẹ laarin awọn eeyan ijagbọ ati awọn obi musulumi ti wọn n se iwọde.Wọn pada wa doju ija kọ ara wọn pẹlu ohun ija oloro'' Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?