Babatunde Kewejo: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń wa ọkọ̀ èrò láì ní ẹsẹ̀ méjééjì ní Ibadan

Babatunde kewejo

Gbogbo ohun tí Olúwa dá dáradára ni.

Ọkùnrin kan ẹni ọdún mọkándínlógójì, Babatunde Kewejo tó ń wa taxi ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ti sọ ìrírí rẹ̀ lórí bí àwọn ènìyàn ṣe máa n fojú kéré rẹ̀ nítorí ipò rẹ̀.

Bábatunde kewejo ló jẹ́ àkàndá ènìyàn tí kò ní ẹsẹ̀ méjéèjì ṣùgbọ́n tó ń lo irin tó fi ń rìn láti wa ọkọ̀.

Ó ṣàlàyé fún BBC pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn ènìyàn bá fẹ́ wọ ọkọ̀ òun, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá ti ri wí pé òun kò ní ẹsẹ̀. ni wọ́n máa ń sá padà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bákan náà ló ní wí pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní àwọn èrò máa ń fojú tẹ́mbẹ́lú òun nítorí ipò tí òun wà ní kété tí wọ́n bá ti fẹ́ wọ ọkọ̀ òun.

Ó ní lọ́pọ̀ ìgbà ní àwọn èrò máa ń bèrè wí pé ṣe òun mọ ohun tí òun ń ṣe báyìí ṣùgbọ́n òun kò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ yìí da omi tútù sí òun lọ́kàn nítorí òun ní ẹbí láti bọ́.

Babatunde Kewejo
Àkọlé àwòrán, Babatunde Kewejo

Kí ló ṣe Babatunde Kewejo kó tó dí ẹni tí kò lẹ́sẹ̀ mọ́?

Babatunde ṣàlàyé pé àrùn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ ló kọ lu òun nígbà tí òun wà ní ọmọdé.

Ó ní gẹ́gẹ́ bí ìyá òun ṣe ṣàlàyé fún òun, nígbà tí àìsàn náà ti mú kí ẹsẹ̀ òun kákò ní ẹnìkan sọ fún ìyá òun pé òun le na àwọn ẹsẹ̀ òun.

Ó fi kun pé lóòótọ́ ló na àwọn ẹsẹ̀ náà ṣùgbọ́n wàhálà mìíràn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹsẹ̀ òun bẹ̀rẹ̀ síní jẹrà títí dé ibi orúnkún.

"Nígbà yìí ni àwọn òbí mi gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn tí àwọn dókítà sí àwọn yóò gé ẹsẹ̀ mi ni."

Ó ní láti ọmọ ọdún méje ni wọ́n ti gé ẹsẹ̀ òun májéèjì.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Ǹ jẹ́ Babatunde Keweje lọ sí ilé ẹ̀kọ́?

Babatunde ní tí ènìyàn bá sọ fún òun pé kabúkabú ní òun yóò ṣe, òun yóò jiyàn ṣùgbọ́n kò sí ohun tí òun fẹ́ bá Ọlọ́run fà.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ladoke Akintola, Ogbomoso ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ètò ìrìnà, tó sì parí lọ́dún 2009.

Ó ní bí òun ṣe lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama pẹ̀lú ẹsẹ̀ òun náà nìyí.

Bákan náà ló ní lẹ́yìn tí òun wáṣẹ́ tí òun kò ríṣẹ́ ni òun bẹ̀rẹ̀ síní wa taxi láti bọ́ ìyàwó àti àwọn ọmọ méjì àti pé òun kò fẹ́ sùn kalẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Ó wá rọ gbogbo àwọn ènìyàn láti yé fojú kéré àwọn àkàndá ènìyàn, kí àwọn àkàndá ènìyàn náà yé wo ara wọn bí ẹni tí Ọlọ́run kò dá dáradára.

Àkọlé fídíò, Ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn ni ojú bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn mí tí àwọn dókìtà sì ní Glaucoma ló fàá