Abba Kyari: Ẹ wo irú àìsàn tó ń ṣe aya Kyari àti ìdí tí adájọ́ ṣe kọ̀ láti gba béèlì ọkọ rẹ̀

Iyawo Abba Kyari to daku nile ẹjọ

Ọrọ fẹ jọ bi ere tiata diẹ loni nileẹjọ giga to wa nilu Abuja nibi ti igbẹjọ ọga ọlọpaa Naijriia Abba Kyari ti n waye.

Eyi ko si se lẹyin bi iyawo rẹ se daku lẹyin ti wọn pari igbẹjọ lonii ti se ọjọ Aje.

Se ni awọn eeyan rọgba yi obinrin naa ka lati doola ẹmi rẹ, ti wọn si gbe kuro nile ẹjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ki lo mu ki iyawo Kyari daku nile ẹjọ?

Asọ dudu ni iyawo Kyari wọ wa sile ẹjọ, to si fẹ lọ di ọkọ rẹ mu, ki o to sadede bẹrẹ si ni mi hẹlẹhẹlẹ.

Ka to wi, ka to fọ, obinrin naa ti daku gbọnran-gandan amọ awọn mọlẹbi to ba BBC sọrọ sọ pe aisan semi-semi (Asthm) lo ni.

Eyi jẹ ọkan lara nkan to sẹlẹ nla to waye nile ẹjọ lonii sugbọn adajọ ti sun igbẹjọ ẹsun kiko oogun oloro ti wọn fi kan Abba Kyari sọjọ mii.

Ni bayii ọjọ Kejidinlọgbọn osu yi ni wọn yoo tẹsiwaju igbẹjọ lori gbigba beeli Abba Kyari ati awọn ọlọpaa mẹrin miran ti wọn jijọ fẹsun kan wọn.

Abba Kyari ati awọn afurasi yoku nile ẹjọ

Nibo ni igbẹjọ de duro lati ibẹrẹ?:

Lọjọ Kẹjọ osu Kẹta ni Kyari ati awọn ọlọpaa mẹ́rin sọ fun adajọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Ẹsun yii nise pẹlu oogun oloro cocaine kilo mẹtadinlogun le diẹ ti wọn ni wọn fẹ ta ati pe wọn gbọna ẹburu yọ ninu oogun oloro cocaine naa, eyi to le diẹ ni ogun kilogiramu.

Adajọ Emeka Nwite lẹyin to gbọ atotonu agbẹjọro Mahmoud Magaji sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Kyari jẹ eleyi ti wọn le gba oniduro rẹ.

Agbẹjọro Kyari yii tun sọ pe Kyari nilo asiko pẹlu agbẹjọro rẹ ki wọn ba fi le gbaradi daada de igbẹjo.

O ni ti Kyari ba si wa lọdọ ajọ NDLEA ko ni le se eleyi bo ti se yẹ.

Agbẹjọro naa fikun pe NDLEA ko ti fun laaye lati le sinmi daada ati lati sayẹwo ẹjọ to wa lọrun rẹ.

O ni wọn n tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ ni bayii.

Abba Kyari le na papa bora ti wọn ba gba oniduro rẹ - NDLEA

Agbẹjọro NDLEA Joseph Sunday gba ile ẹjọ nimọran ki wọn ma se jẹ ki wọn gba beeli Kyari.

Awijare rẹ to fi ẹsẹ ofin gbe lẹyin ni pe, Kyari le na papa bora bi wọn ba fi le gba oniduro rẹ.

NDLEA tun sọ pe jijẹ ọga ọlọpaa ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa tun jẹ anfaani fun Kyari lati sa kuro ni Naijiria, ti ko si ni yọju sile ẹjọ bi wọn ba fi le gba beeli rẹ.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Bawo ni Kyari ti se di ẹni wọn gbe lọ siwaju adajọ?

Ajọ NDLEA sọ pe ọrọ naa bẹrẹ lọjọ kọkanlelogun osu Kini nigba ti Kyari pe ọkan lara awọn osisẹ NDLEA ni Abuja ni nkan bi aago meji ọsan.

Nigba ti osisẹ yii yoo fi de ọdọ rẹ, o ni Kyari sọ pe oun n bọ wa ri i lati jiroro lori ọrọ isẹ kan lẹyin irun Jimọ.

NDLEA sọ pe nise ni Kyari yọju nibi to da ati lasiko to da, ti ko si deena pẹnu lori ohun to ba wa.

''O ni awọn ọmọ isẹ oun kan gba afurasi agboogun oloro kan ti wọn gbe oogun oloro kilogram marundinlọgbọn wọ Naijiria lati Ethiopia.

Kyari wa daba pe ki wọn jijọ se apapin oogun oloro yii, o ni pe oun ati awọn ọmọ isẹ rẹ yoo mu kilo mẹẹdogun ninu oogun oloro naa, tawọn yoo si fi kilo mẹwaa silẹ fawọn to ba fẹ bawọn sẹjọ.

NDLEA sọ pe Kyari ni oun yoo paarọ eleyi to wa lọwọ wọn pẹlu oogun oloro ayederu kilo mẹẹdogun.

Ajọ naa wa pari ẹsun yii pẹlu alaye pe Kyari ni ki osisẹ NDLEA naa ba awọn eeyan rẹ sọrọ, ki awo ma baa ya lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn ni ojú bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn mí tí àwọn dókìtà sì ní Glaucoma ló fàá