Ukraine-Russia Crisis: Wo nkán tí Putin ní òun fẹ kí àlàáfíà tó lè wáyé láàrin Russia àti Ukraine

Awọn ologun ni Ukraine

Ipa to lamilaka ni orileede Turkey nko ninu aawọ to n waye laarin Russia ati Ukraine.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, akitiyan rẹ lati pẹtu si aawọ naa si ti n so eso rere.

Eleyi to jẹ itọka si aseyọri yii ni ipe kan to waye laarin aarẹ Russia Vladimir Putin ati aarẹ Turkey, Recep Tayyip Erdogan.

Nibẹ si ni aarẹ Russia ti sọ awọn nkan to n fẹ ko waye, ki alaafia baa le wa laarin ilẹ rẹ ati Ukraine.

Lọjọbọ ni wọn dijọ sọrọ lori foonu, ti olubadamọran ati agbẹnusọ si aarẹ Turkey, Ibrahim Kalin si n tẹti si ọrọ wọn.

Àkọlé fídíò, Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀

Ki wa ni Russia sọ pe oun n fẹ ẹ?

Awọn nkan ti orileede Russia fẹ pin si ọna meji.

Akọkọ nibẹ pin si awọn koko mẹrin pataki kan ti Putin sọ pe ko soro fun orileede Ukraine lati se.

Akọkọ ni pe ki o gba lati mase darapọ mọ ajọ NATO.

Saaju ipade naa, aarẹ Zelensky ti sọ nkan to jọ mọ eleyi. pe ilẹ Ukraine ko ni darapọ mọ ajọ NATO.

Awọn nkan mii na wa labẹ isọri yii to se pe Russia fẹ, ki oju ma baa fi le ti i.

Awọn nkan iyoku ti Russia n fẹ ki ogun to n gbe ti Ukraine le tete pari:

  • Ki Ukraine bẹrẹ igbesẹ didẹwọ kiko nkan ogun jọ ki o ma ba le jẹ ipalaya fun Russia
  • Wọn gbọdọ daabo bo ede Russia ni ilẹ Ukraine.
  • Ẹlẹkẹẹta si ni se pẹlu ki wọn jawọ kuro ninu iwa to tako ti Nazi

Eleyi jẹ nkan ti yoo soro lati gba fun aarẹ Zelensky, ti oun gangan jẹ ẹya Jew to korira Nazi sugbọn aarẹ Tukey lero pe ko yẹ ko ma le gba to ba ya.

Àkọlé fídíò, Plastic Recycler: Asade Abdulsalam ni kìí ṣe gbogbo ìdọ̀tí ni ẹ̀gbin, owó ni

Isọri nkan keji ti Russia beere:

Ibi ti isoro wa ree.

Aarẹ Putin si sọ ninu ipe rẹ pẹlu aarẹ Turkey pe oun yoo ni lati yanju aarin yii lojukoroju pẹlu aarẹ Zelensky ni.

O ni ayafi bẹẹ nikan lawọn yoo fi le fẹnu ko lori awọn nkan toun n beere fun wọnyi.

Arakunrin Zelensky ti sọ tẹlẹ pe oun fẹ foju kan aarẹ Putin.

Ọgbẹni Kalin to jẹ agbẹnusọ aarẹ Erdogan ko sọ pato awọn nkan ti aarẹ Putin fẹ jiroro le sugbọn o ni o nise pẹlu ipo ti ilu Donbas to wa ni ila oorun ati awọn ilu mii to ja kuro lara Ukraine wa

Bẹẹ lo fẹ ki wọn yanju ọrọ lori ipo ti ilu Crimea naa yoo wa.

Toun ti pe Ọgbẹni Kalin ko sọ ẹkunrẹrẹ alaye lori ọrọ yii, Russia yoo fẹ ki Ukraine jọwọ agbegbe yii fun oun.

Eleyi yoo si lagbara diẹ.

Lakotan erongba ni pe Russia yoo tun fẹ ki Ukrane gba pe awọn lawọn ni Crimea, ti Russia fipa gba lọdun 2014.

Bi ọrọ ba ri bẹẹ, eleyi naa ko ni rọrun lati gba fun Ukriane.

Amin iyasọtọ kan

Olóyún kan àti ọmọ inú rẹ kú nígbà ti Russia sọ àdó ikú sílé ìwòsàn ní Ukraine

Oku oloyun ati ọmọ inu rẹ ti wọn gbe sinu kẹkẹ alaisan

Oríṣun àwòrán, Associated Press

Obinrin alaboyun kan to fẹ́ bimọ ati ọmọ inu rẹ ti dagbare faye lasiko ti ikọ ogun Russia yin ado oloro si ile iwosan to wa nilu Mariupol.

Awọn aworan ikọlu naa safihan obinrin ọhun ti wọn gbe sinu kẹkẹ alaisan, eyi to ba ni lọkan jẹ julọ.

Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin AP ti salaye, isẹ abẹ pajawiri ni wọn fi gbẹbi fun obinrin naa lati doola ọmọ inu rẹ amọ o se ni laanu pe awọn dokita ni ẹpa ko boro mọ.

Ikọ ọmọ ogun Russia lo ti wa n wi awijare lori idi ti wọn se kọlu ile iwosan naa.

Wọn ni awọn alakakiti ọmọ ilẹ Ukraine lo ti sa lọ sile iwosan naa lati fori pamọ sibẹ pẹ́lu afikun pe ile iwosan naa ko sisẹ ipese ilera mọ.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Amọ awọn alasẹ ijọba Ukraine ti sẹ lori ẹsun yii, ti wọn si n naka aleebu si orilẹede Russia pe o hu iwa ọdaran loju ogun ni.

Ukrain ni se ni awọn ologun Russia n dana bo ilegbe araalu:

Wayi o, ikọ olutọju pajawiri nilẹ Ukraine ti kede pe se ni ọkọ ijagun ofurufu Russia n da ado iku bo awọn ilegbe kan ni Kyiv.

Ẹmi eeyan kan ni wọn lo ti bọ sinu isẹlẹ naa nigba ti se eto itọju oju ẹsẹ fun eeyan mẹsan mii to farapa ninu ikọlu naa.

Bakan naa lo fikun pe oun ti doola ẹmi eeyan mẹẹdogun, to si ko eeyan mẹtalelọgọta kuro ninu awọn ilegbe ti wọn n da ado oloro bo naa.

Awọn osisẹ adoola ẹmi to n sisẹ pajawiri lawọn ilegbe ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, State Emergency Service of Ukraine

Awọn osisẹ adoola ẹmi to n sisẹ pajawiri lawọn ilegbe ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn osisẹ adoola ẹmi to n sisẹ pajawiri lawọn ilegbe ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters