Kidnapping by Dispatch Rider: Ọlọ́pàá Eko ní ọlọ́kadà akẹ́rù tí wọ́n ka ọmọ mọ́ lọ́wọ́, kìí ṣe gbọ́mọ́gbọ́mọ́

Lovina ati Williams

Oríṣun àwòrán, Instagram/linda ikeji blog

Àkọlé àwòrán, Iya ọmọde naa sọ pe 'uncle' ni Williams jẹ fun ọmọ oun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

A se o dara lati wadi ohun gbogbo daju, ka le di eyi tii se otitọ mu.

Arabinrin kan ti jade sita pe oun lo ni ọmọde kan ti awọn araalu ka mọ ọwọ ọlọkada, abani fi ẹru ranṣẹ kan nipinlẹ Eko.

Ọjọ Ẹti ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to safihan bi ero ṣe pe le ọkunrin ọlọkada naa lori, ti wọn si n lu u pe o ji ọmọ gbe ni agbegbe Sangotedo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin sọ pe inu apoti ti ọlọkada naa so mọ ẹyin ọkada rẹ fun ẹru kiko, lo gbe ọmọ naa si.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, fi ikede sita pe oun n wa ọlọkada naa.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ni ẹnikẹni ko fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, agbẹnusọ wọn, Adekunle Ajisebutu, sọ pe awọn yoo se iwadii iṣẹlẹ naa.

Fura mi ni mo gbe ọmọ mi fun ọlọkada akẹru naa - Iya ọmọ

Ṣugbọn ọrọ gba ibomiran yọ lọjọ Aiku, pẹlu bi obinrin kan sẹ sọ pe oun ni iya ọmọ naa, ati pe funra oun ni oun gbe ọmọ fun arakunrin ọlọkada to jẹ mọlẹbi oun.

Ninu fidio kan to tun ti wa lori ayelujara bayii, obinrin naa duro pẹlu ọkunrin kan to gbe ọmọde kan dani.

Bakan naa ni obinrin miran, to sọ pe oun ni oludasilẹ ileeṣẹ ọlọkada abanifiẹru ranṣẹ naa, sọ pe aṣiṣe ati aṣimu ni iṣẹlẹ ọhun.

O ni awọn to mu ọkunrin naa ko ṣe iwadii daadaa, ki wọn o to bẹrẹ si ni fi iya jẹ.

Emi ni mo ni ileesẹ akẹru ti ọlọkada n ba sisẹ:

Yatọ si eyi, o ni awọn ti lọ si ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ajah, ati olu ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Ikeja, lati fidi ọrọ mulẹ.

Obinrin naa sọ pe awọn araalu fi ayederu iroyin jiji ọmọ gbe naa ba iṣẹ oojọ oun jẹ.

O ni aṣisẹ kan ṣoṣo ti ọlọkada naa ṣe ni pe o gbe ọmọ naa sori ọkada jade lọ si aarin igboro.

Bakan naa ni ẹni to pe ara rẹ ni iya ọmọ naa sọ pe funra oun ni oun gbe ọmọ naa fun ibatan oun.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Alajọgbele ni iya ọmọ ati ọlọkada akẹru, ọmọ naa si moju ọlọkada pupọ - Ileesẹ ọlọpaa Eko

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lowurọ ọjọ Aje, wọn ni ọkunrin ọlọkada naa, Williams Tadule, gba aṣẹ lọwọ obinrin kan to n jẹ Biturs Lovina, lati gbe ọmọ rẹ, ọmọ osu mẹwaa jade.

Atẹjade naa sọ pe alajọgbele ni Tadule ati Biturs, ti ọmọde naa si faramọ ọlọkada naa daadaa.

"Ọlọkada naa fẹ lọ ra nkan laarin adugbo lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta ti wọn ba ọmọ lọwọ rẹ. Ọmọ naa fẹ ẹ ba lọ, ariwo ẹkun ro n sun lo si mu ki iya rẹ yọnda pe ko gbe dani lọ si ibi to n lọ."

Ọgbẹni Ajisebutu sọ pe kii ṣe inu apoti ẹru lo gbe ọmọ naa si, tako nkan ti awọn araalu ṣe fi ẹsun kan Williams.

Amin iyasọtọ kan

Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n bá ọmọdé nínú àpótí ọlọ́kadà "dispatch rider" l'Ekoo?

Àwòrán ọlọ́kadà

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Àwòrán ọlọ́kadà

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń paná ọ̀kan ní òmíràn ń rú.

Bí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko ṣe ń kọ ha! ha! lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọmọdébìnrin Bamise tí wọ́n bá òkú rẹ̀ lójú títì lẹ́yìn tí ó wọ ọkọ̀ BRT tí wọn kò ì tíì dánu dúró, tuntun mìíràn tún ti wérídé ní agbègbè Ajah bákan náà.

Ọwọ́ àwọn ará ìlú ti tẹ ọkùnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ àwọn ilé iṣẹ́ tó máa ń fi ọ̀kadà gbé àwọn ọjà tí ènìyàn bá rà lọ sí ilé wọn ìyẹn "dispatch rider" fẹ́sùn pé ó jó ọmọdé kan gbé.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ìwé ìròyìn Daily Trust fi léde, ọmọdé kékeré kan ni wọ́n bá nínú àpótí tó yẹ kó jẹ́ pé ẹrù tí arákùnrin ọlọ́kadà náà bá fẹ́ lọ gbé fún àwọn tó ni í ló yẹ kó wà níbẹ̀.

Ní agbègbè Sangotedo ní ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n ní ọwọ́ ti tẹ arákùnrin tí ẹnikẹ́ni kò ì tíì mọ ọrúkọ rẹ̀ tàbí ẹyẹ tó ṣu ú báyìí.

Lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter ni ẹnìkan tí kọ́kọ́ fi fọ́nrán tó ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń péjọ na ọkùnrin náà léde tí wọ́n sì ń wọ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.

Ẹni kan lábẹ́lẹ̀ nínú fọ́nrán náà gbé ọmọdé kan lọ́wọ́ tó sì ń pariwo pé ọmọ tí arákùnrin náà jí gbé nìyìí.

Lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, a kò lè fi bí ọmọ náà ṣe dé inú àpótí náà múlẹ̀.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wí?

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ní àwọn ti rí fọ́nrán tó gba orí ayélujára kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ jíjí ọmọ gbé ní agbègbè Sangotedo.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Adekunle Ajisebutu fi síta lọ́sàn òní ní lóòótọ́ ní àwọn ń rí fọ́nrán níbi tí àwọn ènìyàn kan ti ń fẹ̀sùn kan ọkùnrin ọlọ́kadà ilé iṣẹ́ ìkẹ́rù kan pé ó jí ọmọ gbé.

Àmọ́, Ajisebutu ní ẹnikẹ́ni kò mú ẹjọ́ náà tàbí fi ọ̀rọ̀ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá kankan débi tí àwọn ọlọ́pàá yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tó yọ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kankan kò mú ẹjọ́ náà tọ àgọ́ ọlọ́pàá kankan lọ, Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Abiodun Alabi ti pàṣẹ pé kí àwọn ṣe àwárí ọkùnrin náà àti àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ ọmọdé náà láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó yẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.