Roheem Bamimore: Ìlú Saki gbóná fún ìwọ́de nígbà tí wọn rí òkú ọmọ ọdún mẹ́jọ tí wọn jí gbé

Roheem Bamimore ati awọn afurasi to pa

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ara meeriri ni isẹlẹ to waye nipinlẹ Oyo, eyi to mu kawọn araalu tu yẹẹyẹ bọ sita.

Ọpọ eeyan to si gbọ nipa isẹlẹ naa lo n kawọ leri pe ki ni iru eyi, ti ara si n ta wọn lori ẹmi ọnọde to ba isẹlẹ naa lọ.

Ilu Saki to wa ni agbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo lasiko ni ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹjọ kan sadede di awati, eyi to da ara adugbo si wahala.

Ọmọdekunrin naa, Raheem Bamimore tii se ibeji, lo di awati ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹrin osu Kẹta ọdun 2022 nilu Saki.

Amọ se ni wọn sadede ba oku rẹ nile akọpati kan to wa ni opopona Ogbooro ladugbo Al-Barka ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa osu kẹta.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya

Bawo ni Roheem Bamimore se rin, to fi di awati?

Iroyin naa ni aago mejila aabọ ọsan ni wọn ti ile ẹkọ de lọjọ Ẹti, ti oloogbe naa si gbe apo iwe rẹ silẹ, to si sare jade lọ siat.

Amọ nigba ti ko pada sile mọ ni awọn obi rẹ kede pe wọn n wa ọmọ naa.

Awọn obi rẹ lero pe Roheem gbagbe nnkan sile ẹkọ rẹ, lo sare pada lọ mu nitori opin ọsẹ ti wọn wa amọ lati igba naa, ni wọn ko ti fi oju kan ọmọ ọhun.

Gẹgẹ bi ibeji Roheem ti salaye, bi awọn se de ẹnu geeti ile awọn, ni awọn ọkunrin kan to jẹ ara adugbo awọn sẹwọ si ekeji oun pe ko wa, ko to di pe o wọnu ile.

Idi si ree to fi sare jade pada ni kete to gbe apo iwe rẹ silẹ tan ninu ile.

Bawo ni wọn se ri oku Roheem?

Lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ti n wa Roheem, ni wọn ri oku rẹ nile akọpati lọjọ Aiku, ti awọn aladugbo si figbe ta lọ sọdọ ikọ Amotekun.

Koda, baba awọn ọmọkunrin meji to ji Roheem gbe, ẹni to maa n kiri oogun eku, si lo kọkọ ri oku rẹ, to si pariwo fun ara adugbo.

Awọn ikọ Amotekun yii si lo lọ mu awọn ọkunrin to sẹwọ si Roheem nigba to ti ile ẹkọ de, ni akara isẹlẹ bi ọmọdekunrin naa se di awati ba tu sepo.

Awọn osisẹ Amotekun naa si lo fa awọn afurasi ajọmọgbe ọhun le ileesẹ ọlọpa lọwọ nibi ti wọn ti jẹwọ iwa ika ti wọn hu.

Àkọlé fídíò, ''N15m làwọn Fulani ajínigbé kọ́kọ́ bèèrè kí wọ́n tó gba N2.5m ọ́wọ́ wa l'Abuja''

Alaye ree lori idi ta fi ji Roheem gbe - Afurasi

Awọn afurasi mẹtẹẹta ti wọn fi ẹsun iku Roheem kan, ni wọn wa lati idile kansoso, ti wọn si jẹ baba ati ọmọkunrin rẹ meji.

Orukọ wọn ni Padun Abdulrazaq tii se baba wọn, pẹlu Waliu Abdrazaq ati Illiaz Abdulrazaq ti awọn mejeeji jẹ tẹgbọn taburo.

Nigba ti wọn n jẹwọ idi ti wọn se ran ọmọde naa lọrun ọsan gangan, ọkan lara awọn afurasi naa ni awọn kan fẹ gbe ọmọ naa lati gba owo lọwọ baba rẹ ni.

O ni se ni awọn tan Roheem wa sile akọpati naa lati ji gbe amọ kia ni ọmọ naa da awọn mọ nitori pe adugbo ni awọn dijọ n gbe.

Ọna lati mase jẹ ko tu asiri awọn lori bi awọn se fi iya jẹ ni igbekun awọn, ti awọn si so mọlẹ, lo mu ki Waliu fun ni oogun ekute jẹ.

Mangoro la fi tan Roheem, ka to ji gbe:

Nigba to n salaye bo se rọrun fun wọn lati ji oloogbe naa, Illiaz salaye pe mangoro ni awọn fi tan ọmọ naa gbe lọ.

"Baba Roheem lowo lọwọ, a si fẹ gba owo lọwọ rẹ la se ji ọmọ naa gbe. Waliu lo tan Roheem wa sinu ile akọpati pẹlu Mangoro.

Amọ emi kilọ fun pe ko fi ọmọ naa silẹ nitori pe ọmọde kekere ni amọ o ni oun ko le fi silẹ rara nitori pe ọmọ naa da oun mọ.

Amọ lẹyin igba diẹ, lo ba fun Roheem ni oogun eku jẹ, to si pa."

Àkọlé fídíò, 'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'

Araalu Saki se iwọde sọdọ ọlọpaa lati fi ẹhonu han lori iku Roheem:

Itara abiamọ lori iku ọmọde yii si lo mu kawọn eeyan ilu Saki dide lati fi ẹhonu wọn han sọdọ awọn ọlọpaa.

Nibẹ si ni wọn ti n beere fun idajọ ododo lori iku ọmọde naa, asiko yii naa si ni awọn janduku darapọ mọ wọn.

Ọga ọlọpaa fun ẹkun keji ileesẹ ọlọpa to wa nilu Saki, Oluyinka Oluokun Kolawole tiẹ salaye erongba iwọde naa si agọ ọlọpa lori eto ori redio kan.

O ni awọn afẹhonuhan naa wa sagọ ọlọpaa lati wa ba ibẹ jẹ ni, ki wọn si sọ ina sibẹ pẹlu.

Amọ o ni Ileesẹ ologun, ọlọpaa ati Amotekun dijọ pawọpọ bu omi pa ina iwọde ọhun lai gbẹmi ẹnikẹni.

Kolawole wa fi ọwọ idaniloju sọja pe awọn eeyan ti aje iwa ika naa ba si mọ lori yoo fi imu ko ata ofin.

Àkọlé fídíò, Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá