Kidnapping In Oyo: Ìjọba tú àṣírí ọ̀nà tuntun tí ajínigbé ń gbà jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé

Oríṣun àwòrán, OYSG
Yoruba ni igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere ni a ti n lọ ọ.
Idi ree ti ijọba ipinlẹ Oyo se n figbe ta fawọn obi ati araalu lori ọna ẹburu ati ọgbọn alumọkọrọyi tawọn ajinigbe n gba bayii lati sisẹ ibi wọn.
Ninu atẹjade kan ti ijọba Oyo fisita lati ipasẹ akọwe agba fun ileesẹ eto ẹkọ, Arabinrin Atere, ni ijọba ti n rọ awọn akẹkọ, olukọ ati obi lati mase wọ mọto ọfẹ lati ọdọ ẹni ti wọn ko mọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Iyorchia Ayu tó dí Alágá tuntun fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP
- Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
- Òjò owó àti ẹbùn ń rọ fún Iyabo Ojo fún ayẹyẹ ọdún kan ikú ìyà rẹ
- Ayẹyẹ ìwúyè Grand Mufti wáyé ní Iwo, ọ̀pọ̀ adarí ẹ̀sìn Islam péjú
- Agbébọn ṣe ń gba owò ilẹ̀ ní Ariwa, agbèrò ń gbà ní gúúsù, kò sí ìyàtọ̀ - Lai Muhammed
- Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo pàpà wáyé lẹ́yìn tí jàǹdùkú mú alága ìbò abẹ́nú nígbèkùn
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
Ijọba ni o n bọ, o n bọ awọn laa dẹ de amọ lojumọ toni, oju ni wọn n mu to, o si yẹ kawọn araalu gbọ ikilọ yii, ki wọn ma baa ji wọn gbe.
Ijọba ni awọn ajinigbe ti n dibọn bii akẹkọọ nipa wiwọ asọ ile ẹkọ, ki wọn le dara pọ mọ awọn akẹkọọ lati ji wọn gbe.

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government
Atẹjade naa salaye pe ilu Ibadan ni awọn ajinigbe ti n dibọn bayii julọ lati ji awọn akẹkọọ gbe lọ, ti wọn si n rọ awọn obi lati luaago ikilọ yii fun awọn ọmọ wọn.
Atẹjade naa ni "Wọn ti dari mi lati sọ fun yin pe o se dandan ki gbogbo araalu maa fi oju sọri, ki wsn si mase maa wọ ọkọ ọfẹ.
Idi ni pe iwadii ọtẹlẹmuyẹ ti sisọ loju rẹ pe se ni awọn agbofinro n wọ asọ ile ẹkọ lati maa ji awọn akẹkọọ gbe.
Tawọn ọmọ naa ba si ti wọ inu mọto awọn ajinigbe yii, ni wọn yoo gbe wọn lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.
A wa n rọ awọn eeyan ti ọrọ yii gberu lati kilọ fawọn ọmọ wọn pe ki wọn ko ara wọn nijanu, ki wsn si mase wọ ọkọ ọfẹ."



















