RCCG Directorate of Politics: Ìjọ RCCG fèsì sí awuyewuye pé torí Osinbajo ni ẹ̀ka òṣèlú ṣe wà ní ìjọ náà

Pasitọ Enoch Adeboye

Oríṣun àwòrán, RCCG

Ijọ Redeemed Christian Church of God eyi ti Pasitọ Enoch Adeboye n dari ti sọrọ sita lori iroyin to jade pe wọn da ẹka eto oṣelu kalẹ ninu ijọ naa.

Lori igbesẹ yii, kete ti awọn eniyan rii ni awuyewuye ti n lọ lode pe nitori Pasitọ to tun jẹ ọmọ ijọ naa to jẹ igbakeji aarẹ Naijiria, Adajọ agba, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ni wọn ṣe ṣe e.

"Haaa, tori erongba Yemi Osinbajo lati dije dupo aarẹ Naijria lọdun 2023 ni ijọ RCCG ṣe da a bi ọgbọn". Eyi ni ọrọ to n jade lẹnu awọn mii.

Bakan naa ni awọn mii n sọ pe ohun to dara ju ni ijọ RCCG ṣe yii toripe kii ṣe Osinbajo nikan ni ọmọ ijọ RCCG to wa ninu oṣelu o si yẹ ko jẹ ọna lati maa ṣọ iṣe wọn ni ipo ti wọn ba wa.

Nitori naa, ijọ naa ti sọ pe irọ ni o, kii sii ṣe tori igbakeji aarẹ Osinbajo tabi tori ẹnikẹni to ba ni erongba oṣelu lọdun 2023 ni awọn ṣe gbe ẹka tuntun naa kalẹ.

Adari ẹka iroyin ati ọrọ to kan araalu, Pasitọ Olaitan Olubiyi sọ eyi ninu esi rẹ si ibeere ileeṣẹ iroyin Punch.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ẹka ọrọ oṣelu ijọ naa jẹ eyi ti wọn da silẹ lati ṣe ilanilọyẹ fawọn ọmọ ijọ ki wọn kopa gidi ninu oṣelu to fi mọ ki wọn gba kaadi idibo alalopẹ wọn ṣaaju idibo gbogboogbo ti ọdun 2023.

Bakan naa ni Olubiyi sọ pe ijọ RCCG ti n ṣe ilanilọyẹ nipa oṣelu fawọn ọmọ ijọ rẹ lati igba ti ijọba ologun ti gbe ijọba fun alagbada latọdun 1999 ko si si tuntun tabi babara ninu igbesẹ naa.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

O ni awọn Kristẹni ko le tẹsiwaju láti maa jẹ ki wọn gbe wọn mọra nipa yiyọwọ kuro ninu oṣelu nitori gbogbo eeyan ipinu yiyan adari ninu oṣelu yoo ni ipa lara rẹ.

Agbẹnusọ ijọ RCCG yii wa tubọ gba awọn ijọ to ku ni Naijiria ati ibi gbogbo ni imọran pe ki wọn fi ohun ti awọn ṣe yii ṣe awokọṣe nipa ṣiṣe ilanlọyẹ fawọn ọmọ ijọ wọn ki wọn maa kopa ninu oṣelu.

Ninu atẹjade kan ti igbakeji oludari ijọ RCCG, Pasitọ John Odesola fọwọ si eyi ti wọn fi ranṣẹ si gbogbo ẹka ijọ RCCG ni wọn ti sọ sinu ẹ pe wọn da ẹka naa silẹ fun idanilẹkọ awọn ọmọ ijọ ni.

"A n beere fun pe ki ẹ yan oludari kan ni ẹkun ti ẹ wa gẹgẹ bi adari kiakia ti yoo maa ṣakoso ati ki ẹ si ṣe bẹẹ ni gbogbo ẹka ijọ. Idi eyi ni lati ṣeranwọ kikọ awọn eeyan wa to nifẹ lati kopa ninu oṣelu ki si ṣeto atilyin fun wọn nigba ti o ba nilo".

Ijọ RCCG ni ijọ to tobi ju lọ ni Naijiria to si ni ẹka ni awọn orilede agbaye to le ni ẹẹdẹgbẹwa. RCCG ni awọn ilumọọka ọmọ ijọ ati Pasitọ ninu ijọba lara wọn si ni igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo, iyawo adari ẹgbẹ oṣelu APC, Remi Tinubu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe Bola Tinubu ti kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ, Yemi Osinbajo ko tii kede erongba tirẹ.

Ẹwẹ, alatilẹyinati ololufẹ rẹ ti n rọ ọ lati kede ko si tẹwọ gba eku ida iṣejọba lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba

Ki ni ijọ Redeem Christian Church of God fẹ fi ẹka ọrọ oṣelu to da silẹ ṣe ni ibeere ti ọpọ n beere?

Eyi waye ni kete ti iroyin jade pe ijọ naa ti da ẹka kan silẹ fun ọrọ oṣelu ati iṣejọba ṣaaju eto idibo apapọ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023.

Ijọ RCCG kede rẹ ninu iwe kan to kọ si awọn ẹka ati oṣiṣẹ rẹ pe ẹka tuntun yii ni yoo maa dari eto gbogbo nipa awọn ọmọ ijọ naa to ba fẹ dije fun ipo oṣelu lọdun 2023.

Bakan naa ni ijọ RCCG tun kede orukọ Pasitọ Timothy Ọlaniyan to jẹ oluṣọaguntan fun ẹkun kejila nipinlẹ Eko, Lagos Province 12 gẹgẹ bi adari ẹka naa.

Wọn wa kan sawọn oluṣọaguntan lẹkun, ipinlẹ ati agbegbe gbogbo lati yan awọn eeyan ti yoo mojuto ẹka yii lagbegbe koowa wọn.

iwe naa

Oríṣun àwòrán, other

Ki lo wa ninu iwe naa?

Iwe naa ti akori rẹ jẹ RCCg/AGO/ADM/AA.MEMO/20/01/2022 ti igbakeji pasitọ agba ijọ RCCG, Pasitọ J.F. Ọdẹṣọla buwọlu sọ ọ sinu rẹ pe:

"A n kọ iwe yii lati fi to yin leti pe awọn alaṣẹ iṣẹ iranṣẹ yii ti da ẹka amojuto ọrọ oṣelu ati iṣejọba ninu ijọ RCCG.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Nitori eyi, Pasitọ Timothy Ọlaniyan, alakoso ẹkun ikejila nipinlẹ̀ Eko (lagos Province 12) lati maa ṣe akoso ẹkoso ẹka yii.

A rọ ẹyin naa lti yan awọn eeyan lẹkun yin lati mojuto ẹka yii ki ilana yii lee wa kaakiri gbogbo ẹka ati ẹkun.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Ẹ gbọdọ fi akọsilẹ nipa gbogbo awọn ti ẹ ba yan ranṣẹ si ọfiisi igbakeji alamojuto agba iṣẹ iranṣẹ yii to n mojuto ọrọ iṣakoso."