Joseph Adelakun on Olusegun Obasanjo: Ara Obasanjo ni mo ti kọ́ ìwà àìjalè

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Baba Obasanjo ko jale, ko dẹ fẹ ọ̀lẹ eniyan, titi di ọla mo ṣi maa n ranti wọn ti mo maa n fi wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun".

Gbajumọ olorin Kristẹni lati igba atijọ wa, Joseph .A. Adelakun ti ọpọlọpọ mọ pẹlu akọle orin rẹ, "Amọna tete bọ" jẹrii nipa aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Aremu Obasanjo pe adari ti ọwọ rẹ mọ ni ti ko ji owo lasiko iṣejọba rẹ.

"Olootọ kii tẹ ẹni, Ọlọrun lo maa n tẹ ẹni fun olootọ, awọn eeyan ko dẹ ki n gba tiwọn tori o maa ṣe nkan bo ṣe yẹ ko jẹ".

J.A Adelakun ni gẹgẹ bii ologun, awọn ẹbun ati imọ ti oun ni yatọ si mimọ iṣẹ ogun lasiko ti oun n ṣiṣẹ , Oloye Obasanjo lo jẹ ki oun nii.

Bakan naa, o ni awọn owo kan wa fun Aarẹ ti awọneeyan maa n yi iwe lati gbe e jade fun ara wọn, o ni Obasanjo ko jẹ ki awọn fọwọ kan owo yii oun gan ko si fi ọwọ kan an "ayafi to ba fẹ ki wọn na a fun ẹ".

O fi kun un pe Iranṣẹ Ọlọrun ni Oloye Olusegun Obasanjo.

Ajihinrere J.A Adelakun gangan ni orukọ rẹ ṣugbọn ko sẹni to fẹrẹẹ mọ agba olorin ẹmi yii pẹlu orukọ rẹ bikoṣe "Amọna tete bọ" eyi tii ṣe akọle orin to sọ ọ di olokiki laye.

O ti sọrọ ni pa bi oun funrarẹ ṣe ba Jesu pade lasiko to wa lẹnu iṣẹ ologun gẹgẹ bi ẹni to maa n mu oogun "Claro" ti wọ́n fi n moriya laye igba yẹn tẹlẹ. Ninu apa keji ifọrọwanilẹnuwo yii, lo ti sọrọ nipa Aarẹ orilẹede to ti ba ṣiṣẹ ri fun ọpọlọpọ ọdun.