Bamise Lagos BRT Murder: Àwọn ìbéèrè rèé tí ẹbí wà fẹ́ ìdáhùn sí láti ọ̀dọ̀ ìjọba Gómìnà Sanwo-Olu

Baba Oluwabamise Ayanwole to kan agbako iku lẹyin to wọ ọkọ akero BRT ni ipinlẹ Eko, naa fi sọrọ sita ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ pẹlu BBc Yoruba to si n beere fún ìdájọ́ òdòdó.
Mọlẹbi arabinrin naa sọ pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ko bikita nipa iku ọmọ awọn.
Amọṣa o ni ti ijọba ipinlẹ̀ Eko, kete ti iku Bamise sẹlẹ ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi atẹjade sita lati ba mọlẹbi naa kẹdun iku Bamise.
Ninu atẹjade ọhun, o sọ pe awọn fẹ fi da araalu loju pe ko si ewu ninu wiwọ bọọsi akero ati pe awọn ba mọlẹbi kẹdun iku Bamise gidi gan.
Bakan naa lo ni titi de kulẹ kulẹ ọrọ yii ni awọn yoo ṣe ọfintoto ti otitọ yoo si leke.
"A ko mọ ibi ti Bamise wa lati igba ti o wọ ọkọ akero ni agbegbe Chevron ni Lekki ni ọna Oshodi ni Oṣu Keji ọjọ 25, kí ó tó di pé wọn dédé pé wá pé wọn rí òkú rẹ".
Baba bamise sọ pé kí gómìnà ipinle Èkó gbe igbesẹ kíákíá kí wọn si ṣe olóòótọ́ níbi tí àṣírí ibi bá wá lori ọ̀rọ̀ iku Bamise kí wọn túu jáde.
Àwọn ara àdúgbò ilé àwọn òbí bamise gan kígbe síta wípé àwọn fẹ́ idajọ òdodo lórí ikú Bamise.
Ìkan lára àwo ara àdúgbò naa sọ wípé kí Gomina Sanwo-Olu dìde gbe igbesẹ, torí wípé àwọn ọmọ àwọn n lọ sí ilè ẹ̀kọ́ ọkàn àwọn òbí ó sì balẹ torí wípé àwọn ọmọ àwọn maa wọ ọkọ BRT lọ sí ilé ẹ̀kọ́.
Ọrọ kan ṣoṣo ti o jade lati ẹnu ẹgbon bamise ni tirẹ ni "idajọ" eyiti o sọ loke ohun rẹ lakoko ti awọn obinrin n ṣe iwọde.
Mọlẹbi ni kaka ki Sanwo-Olu yọju sawọn lati kẹdun lori iku ọmọ awọn, nise ni Sanwo-Olu gba ijo to si n se faaji lalai kọbi ara si ipo tawọn wa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro mọlẹbi fi sita ni ọrọ yii ti jẹyọ.
Agbẹjọro Ayo Ademiluyi sọ pe lọjọ Keji ọjọ ti gbogbo aye n kẹdun iku Ayanwole lẹyin ti wọn ri oku rẹ, nise ni Gomina n ki ijo mọlẹ ni papa nla Tafawa Balewa Square nilu Eko.
O ni ihuwasi yii dabi ẹni pe o tabuku oku arabinrin yii to si n gba ijo lori rẹ.
"Toun ti iku arabinrin naa laisun ayajọ awọn obinrin lagbaye, iyawo Gomina si tẹ́siwaju lati se ajọyọ ayajọ yii. Pẹlu pe arabinrin kan fẹhonu han tako ajọyọ yii ninu fọnran fidio kan to gbode, eti ikun ni wọn kọ sii ti wọn si mu faaji ayajọ yi se''.
Bakan naa ni Ademiluyi sọ pe ileesẹ to n seto ọkọ akero bọọsi BRT ni ipinlẹ Eko lẹjọ ti wọn yoo dahun si.
O fi kun un pe mọlẹbi kan abuku lọdọ awọn osisẹ ileesẹ ọkọ akero yi lolu ile isẹ wọn nibi tawọn ọlọpaa ti n halẹ mọ awọn nigba ti wọn wa fẹjọ sun lori iku ọmọ wọn.
Saaju lo ni awọn alasẹ ijọba ipinlẹ Eko ti sọ fun awọn pe awọn ti gbe akoso ileesẹ ọkọ akero bọọsi yi le awọn aladani lọwọ.
Awọn aladani yii ni agbẹjọro sọ pe o kan awọn ni abuku nigba tawọn n tọpinpin nkan to sokunfa iku ọmọ wọn.
Agbẹjọro naa wa fi awọn ibeere kan sita to ni o yẹ ki awọn alasẹ ileesẹ ọkọ akero Lagos Bus Services dahun ni kiakia:
1. Ki lo de tawọn alasẹ ileesẹ bọọsi LBSL ko fi ni akọsilẹ kankan nipa awakọ?
2. Ki lo de ti wọn fi gbe ọkọ akero ti ọmọ wa wọ pamọ fawọn araalu?
3. Ki lo de to se pe igba ti wọn ri oku Bamise lawọn ileesẹ yi to dawọ isẹ duro ni ipinlẹ Eko.Se aparo kan ga ju kan lọ nipa fifi ero owo saaju ẹmi ọmọ wa?
Torinaa agbẹ́jọro wa sọ pe mọlẹbi Bamise fẹ ki ileesẹ ọlọpaa mu alasẹ ati oludari ileesẹ ọkọ akero LBSL laarin waki mẹ́rinlelogun.
Se lootọ ni Gomina n jo ni ko pẹ asiko iku Bamise?
Kete ti iku Bamise sẹlẹ Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fi atẹjade sita lati fi ba mọlẹbi kẹdun iku Bamise.
Ninu atẹjade naa o sọ pe awọn fẹ fi da araalu loju pe ko si ewu ninu wiwọ bọọsi akero ati pe awọn ba mọlẹbi kẹdun iku Bamise.
Lootọ ni Gomina sọ ninu rẹ pe awọn yoo ṣapa lati rii pe awọn to mọ nipa iku Bamise foju wina ofin sugbọn ko tii kan si mọlẹbi lati bawọn daro lojukoroju.
Ileesẹ BBC naa foju ri fọnran fidio to gbode nibi ti Gomina ti n ki ijo mọlẹ sugbọn a ko le fidi rẹ mulẹ boya lọjọ keji ti wọn ri oku Bamise ni isẹlẹ yi waye tabi bẹẹ kọ.

















