Staying safe in BRT, public vehicles: Wo àwọn ohun tí o lè ṣe láti dáábò ara rẹ lọ́wọ́ ewu ìjínigbé nínú ọkọ̀ akérò

Oríṣun àwòrán, Others
Iku Ayanwola Bamise lo n je ki ẹ̀ru ba ọ̀pọ̀ eeyan lati maa wo mọ́tò èrò ni Naijiria bayii
Lẹyin iku arabinrin Ayanwola Bamishe to jade lẹyin ti wọn ji i gbe lasiko to wọ ọkọ BRT niluu Eko, ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n woye awọn ohun ti wọn le ṣe lati daabo bo ara wọn ti wọn ba wa ninu ọkọ ọlọpọ ero.
Onimọ nipa aabo ara ẹni, Ogbeni Abolarinwa to je akosemose nipa eto aabo ba BBC soro lori ẹ̀ru naa .
Abolarinwa sọ fun BBC pe eto ara ẹni bẹrẹ lati inu ile titi ọdọ ijọba, kii ṣe nigba ti eeyan baa wọ ọkọ akero nikan lo yẹ ko maa ronu bi yoo dabo ara rẹ.
- 'Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lásíkò àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Timothy Adegoke: Ìyàwó Timothy Adegoke jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́, gbọ́ nípa ìjà tó jà fún ọkọ̀ rẹ̀
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
Gẹgẹ bii awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin, paapaa lawọn ilu nla ni Naijiria bii ilu Eko, Abuja tabi Portharcout, oniruru ibi ni awọn kọlọrọsi ti le kọlu eeyan.
Amọ ti o ba ṣẹlẹ, bi o ṣe le daabo bo ara rẹ ree.
-Jẹ ki ara ile mọ ibi ti o n lọ
-O ṣe pataki ki ẹnikẹni to ba n jade maa jẹ ki awọn ẹbi tabi ara ile rẹ mọ ibi to ba n lọ.
-Ko dara to ki eeyan kan sọ pe "Mo n bọ o" lai sọ ni pato ibi gan ti ẹni naa n lọ.
-Ti eeyan ba sọ ibi to ba n lọ, yoo rọrun lati mọ ibi ti wọn yoo wa irufẹ ẹni bẹẹ si lasiko pajawiri.
- Jẹ ki 'Location' foonu rẹ wa ni titan
Kini pataki titan 'Location' lori foonu rẹ̀?
- Ti eeyan ba tan ẹrọ to maa n ṣapejuwe ibi ti eeyan ba wa silẹ lori foonu rẹ, yoo ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn lati mọ irufẹ ibi ti ẹni bẹẹ waa lasiko pajawiri.
Ti 'location' ori ẹrọ ilewọ eeyan ba wa ni titan silẹ, yoo le ṣapejuwe bi irinajo naa ṣe n lọ.
Igbese wo lo tun ye ki o gbe?
- Jẹ ki awọn eeyan rẹ mọ ibi ti o de duro.
- O ṣe pataki ki eeyan maa fi ọrọ ranṣẹ sile lasiko to ba n rinrin ajo nipa ibi to de duro.
Fun apẹẹrẹ, ti eeyan ba n lọ lati ilu Eko si Benin, ko buru ti irufẹ ẹni bẹẹ ba n fi ọrọ ranṣẹ sile nipa ibito de bii; Shagamu, Ijebu-Ode Ọrẹ, ati bẹẹ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ka awọn akọsilẹ eto abo to wa ninu ọkọ ti o wa
Oniruru ọkọ lo maa n Iawọn akọsilẹ awọn ohun to yẹ ki eeyan ṣe lasiko pajawiri ninu irufẹ ọkọ bẹẹ.
Apẹẹrẹ lilo BRT ọ̀kọ̀ akero ijoba Eko:
Fun apeẹrẹ, ọkọ akero BRT ni 'Emergency Exit Sign' ti eeyan le tẹ lati da ọkọ naa duro ti eeyan ba gbagbo pe ẹmi oun wa ninu ewu.
- Ni nọmba ipe pajawiri agbegbe rẹ ati ti ijọba apapọ lọwọ.
- Gbiyanju lati ni nọmba ipe pajawiri agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe rẹ dani.
Nọmba ọhun le jẹ ti DPO, RRS tabi SWAT ti o sun mọ ọ.
Lọ si ori ikanni ileeṣẹ ọlọpaa loju opo Facebook, Instagram ati Twitter lati bere awọn nọmba naa.
Ẹwẹ, nọmba ipe pajawiri Naijiria ni 112 tabi 119, ti o ba wa loke okun bii ilu Amẹrika, pe 911.
Maṣe gbagbe pe lati inu ile ni iṣọra ti n bẹrẹ, oju si ni alakan fi n ṣọri.
Ire o!
















