MC Oluomo biography: Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa MC Oluomo àti ìdí tí ọ̀pọ̀ ṣe gbàgbọ́ pé alágbára ni

MCOLUOMO

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO

Musiliu Akinsanya, MC Oluomo ni alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Eko, NURTW titi di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun 2022 ti awọn adaei ẹgbẹ naa ni Naijiria da a duro.

Ọdun 2019 si lo gba ipo naa lẹyin to ti jẹ akapo ẹgbẹ fun ọdun diẹ.

Wọn bi MC Oluomo ni ọdun 1975 ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ nipinlẹ Eko bakan naa, amọ iroyin sọ pe ko kawe ju ipele yii lọ nitori pe baba rẹ ku nigba to wa ni kilaasi kẹta.

Iya rẹ ko si ni agbara lati tẹsiwaju ninu bukaata eto ẹkọ rẹ.

Lẹyin naa lo di agbero ọkọ.

Iyawo mẹta ni MC Oluomo ni, o si bi ọmọ mẹsan-an.

Bawo ni irinajo igbe aye rẹ ṣe lọ lẹyin iku baba rẹ

MC Oluomo, lasiko to kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba lọdun 2020 salaye pe, ọmọ ọdun meje ni baba oun jade laye, atijẹ atimu di ọran, iṣẹ agbalẹ oju popo ni iya oun si n ṣe.

Oluomo fikun pe "ọdọ ẹni to ku ni iya fun mama mi nilu Abeokuta la n gbe lọdọ rẹ, Mama mi n gbalẹ titi ni Eko, n ko ri itọju to, ni mo ṣe sa kuro nile lọmọ ọdun mẹtala, ti mo si n ṣe kọndọ lati Abeokuta wa si Eko."

Oluomo tun sisọ loju rẹ pe, ko si ẹnikẹni to kọ oun ni ọkọ wiwa, oun kan n sun ọkọ siwaju diẹ-diẹ ni ori tọọnu ni gareeji bii kọndọ, ni oun fi mọ ọkọ wa.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero ni Eko tun fikun pe, inu iya oun ko dun pe oun n ṣe kọndọ, ti wọn si fẹ mu oun lọ sile ọmọ alaigbọran, ti wọn n pe ni welfare, amọ oun sa mọ wọn lọwọ, ti oun si n sun ita.

O wa yan pe, lootọ ni oun n sun ita tabi inu ọkọ mọju, sugbọn oun ko huwa ọmọ buruku ri, oun kii jale, mu igbo, mu siga tabi ọti, ti oun kii si ṣe ipanle.

Nigba to n sọ idi ti wọn ṣe n pe ni Oluomo, MC ni "Oju popo ni mo gbe dagba, a ko ara wa jọ lati dẹkun iwa ole jija ni Oshodi, ni ọba mẹrinla ṣe fi mi jẹ oye Oluomo ni Isọlọ, orúkọ yii si lo ro mi, ti mo fi de ibi giga."

Irinajo rẹ ninu ẹgbẹ awakọ

Iroyin sọ pe iṣẹ agbero ti awọn kan tun n pe ni kọndọ ni Ọgbẹni Musiliu fi bẹrẹ ni agbegbe Oshodi.

Nigba to ya ni oun naa di awakọ ero, ko to o di pe o dara pọ mọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ National Union of Road Transport Workers, NURTW.

O jẹ oye akapo/alamojuto owo ẹgbẹ ni ẹka NURTW to wa ni Oshodi.

Kẹrẹkẹrẹ, o di alaga ẹka naa.

Wọn pada yan an gẹgẹ bi ọmọ igbimọ alamojuto ẹgbẹ nipinlẹ eko, lẹyin ti alaga ẹgbẹ naa nigba kan, Ọgbẹni Tajudeen Agbede kuro ni ipo.

Ko to o pada jawe olubori gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ NURTW jakejado ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Ọpọlọpọ igba ni orukọ rẹ ti jade ninu iroyin fun idi kan, tabi omiran.

Gbajugbaja si ni nitori isẹ rẹ pẹlu ẹgbẹ awakọ, ati pe alagbara ni, to tun mọ eeyan, koda lagbo oṣelu.

Botilẹ jẹ pe o sọ fun BBC Yoruba pe awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ kii da si ọrọ oṣelu, ọpọ igba ni ahesọ ti jade pe awọn oloṣelu ma n lo wọn lati da eto idibo ru, tabi ṣe awọn isẹ ibi fun awọn oloṣelu.

Lasiko iwọde EndSars to waye ni Naijiria lọdun 2020, awọn oluwọde kọ ounjẹ, omi ati awọn nkan ẹlẹrindodo ti MC Oluomo gbe wa fun wọn ni agbegbe Alausa Ikeja.

Ninu fidio to wa lori ayelujara, awọn oluwode naa n pariwo pe awọn ko fẹ ounjẹ rẹ.

Wọn fi ẹsun kan pe oun lo ran awọn janduku to kọlu awọn oluwọde kan.

MCOLUOMO

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO

Ọpọ igba ni iroyin ti jade pe o ni ibaṣepọ pẹlu ongbotarigi oloṣelu, to tun jẹ gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Bola Tinubu.

Eyi si lo mu ki ọpọ gbagbọ pe alagbara ti ko ṣe e kọlu ni.

Lọdun 2019, awọn janduku kan gún ni ọbẹ ni Ikeja, lasiko to n kopa nibi ipolongo ibo to gbe oludije gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-Olu wọle.

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba