Ogun Robbery: Iléeṣé ọlọ́pàá Ogun ṣe àfihàn afurasí adigunjalè márùn ùn àti ọkọ̀ tí wọn ji gbé

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Ikọ adigunjale ẹlẹni marun un kan to n soro bi agbọn ni agbegbe Iperu/Shagamu/Ode Remo ti ko si pampẹ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun.
Lọjọ Kejila osu Kẹta ni awọn ọlọpaa ẹka ipinlẹ Ogun mu awọn alaburu yi.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa Abimbola Oyeyemi fi sita, o ni ọwọ ba awọn afurasi naa lẹyin ti DPO Iperu gba ipe pe awọn olubi yi n sọsẹ ladugb Ogere.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ! Ìyá ọmọ́ yọjú pé ‘Dispatch Rider’ tí wọn ká ọmọ mọ́ lọ́wọ́, kìí ṣe gbọ́mọ-gbọ́mọ
- Ọ̀nà ti di fáwọn tó kúndùn láti máa yí èsì ìdìbò - Makinde
- Ìyáwó Abba Kyari dákú nílé ẹjọ́ bí adájọ́ ṣe kọ̀ láti gba béèlì ọkọ rẹ̀
- Ìbẹ̀rù kòbókò ló mú mi sá nílé kéú, mo bẹ̀rù ẹgba - Obasanjo
- Wo àwọn òṣèré tíátà tó ti fún Kemi Afolabi lẹ́bùn àtàwọn tó ń kíi lẹ́yìn tó kéde àìsàn rẹ̀
- Amotekun náwọ́ gán àwọn afurasí ìgárá ọlọ́ṣà mẹ́jọ l'Osun
Oyeyemi ni ,Moruf Abidogun, Usman Adeyemi, Fisayo Aliu, Afees Adesina ati Dauda lorukọ awọn afurasi adigunjale to n gba owo ati nkan ini lọwọ awọn arralu ki ọwọ to tẹ wọn.
Gẹgẹ bi Oyeyemi ti se sọ, awọn afurasi yi na papa bora bi wọn ti se foju kan awọn ọlọpaa.
O ni wọn ti gba ọkọ Toyota Corolla to ni nọmba idanimọ GGE 733 FL kan lọwọ eeyan kan ki ọwọ to tẹ wọn.
Wọn gbiyanju ati sa mọ ọlọpaa lọwọ sugbọn ẹpa ko boro nitori awọn ọlọpaa ri wọn mu nigba ti wọn n sa lọ.
Awọn ọlọpaa ni yatọ si ọkọ ti wọn ri gba yi, awọn tun ri ibọn kan gba lọwọ wọn.
Ẹwẹ, Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, arakunrin Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe awọn afurasi yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ fun ẹkunrẹrẹ iwadii

Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasi ajínigbé méjì tí kò fí aráàlú lẹ́mi balẹ́ ní Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọwọ palaba awọn afurasi ajinigbe meji kan ti segi ni ipinlẹ Ogun.
Ileesẹ ọlọpaa Ogun lo kede pe ọwọ awọn tẹ afurasi Jato Abu Bello ati Muhammad Suleiman lori ipa ti wọn ko ninu awọn iṣẹlẹ ijinigbe kan to waye lẹnu lọọlọ yi.
Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa Abímbólá Oyeyemi ti ṣe sọ,ni owurọ kutu ọjọ Àbámẹ́ta tíì ṣe ọjọ Kejìlá oṣù Kẹta ọdun yi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Amotekun náwọ́ gán àwọn afurasí ìgárá ọlọ́ṣà mẹ́jọ l'Osun
- Portable Zazzu pariwo pe wọ́n ti dá ọjọ́ méje pé òun yóò kú
- Ọmọdé méje kú, ọ̀pọ̀ farapa nígbà tí ọ̀rọ̀ di bóòlọ, ko yàgò fún mí
- Tẹ̀gbọ́n tàbúrò jí ọmọ ará àdúgbò gbé láti gbowó, àmọ́ wọn fún ní òògùn eku jẹ
- "Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà"
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
- Ohun tó bá kàn ìlú Ibadan, kàn mí - Gómìnà Ganduje
O ni ipa awọn ẹka otelemuye to n koju ijinigbe lo jẹ kí wọn rí àwọn afurasí yíi mu ni ibuba wọn ladugbo Rounder ni Abéòkúta.
" Lẹyìn tàwọn ọlọpaa wa kẹfin ibi tàwọn afurasi naa wa, awọn pẹlu akẹgbẹ wọn ni Ilupeju ati Lafenwa ni wọn jijọ koju wọn, ti ọwọ si tẹ meji ninu wọn"
Awọn afurasi tu asiri iye eeyan ti wọn ti ji gbe sẹyin:
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun tẹsiwaju pe "awọn afurasi ọhun ti jẹwọ pe ikọ awọn lo ji arábìnrin Ajibola Salimot Adejoke gbe lẹyìn tí wọn tọ lọ sí ilé rẹ tó wà ní adugbo Oke ode"
O ni wọn tun jẹwọ pe awọn l'awọn ji Victoria Oladoyin gbe lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣù Kejì ni adugbo Aboba area ni Sodeke titun, Abeokuta.
Ko tan sibẹ, awọn ọlọpaa tun sọ pe ijinigbe awon ọmọ ìyá meji kan Esther Kehinde ati David Kehinde ni Ayetoro lọjọ kẹta oṣu yi ko sẹyìn awọn afurasi yí.
Diẹ ninu awọn ti wọn ji gbe yii ti darukọ awọn ajinigbe naa gẹgẹ bí ẹni tó jí wọn gbe.
Ẹwẹ Komisana ọlọpaa CP Lanre Bankole, ti ni k'awọn ọlọpaa mura s'isẹ lati ri pe ọwọ tẹ awọn ọmọ ìkọ ajinigbe naa to sẹku.

EFCC ti ju Aishatu Arowojobe sẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá l'Ékòó nítorí ẹ̀sun jìbìtì, wo ohun tó ṣe

Oríṣun àwòrán, @EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Eko ti fi oju iyale ile kan han sita.
EFCC ni pe Aishatu Arowojọbẹ ba ile ejo lori ẹsun jibiti, ile ẹjọ naa si ti juu sẹwọn ọdun mẹwaa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu iwa jibiti ati ole jija la gbọ pe ajọ EFCC fi kan Aishatu
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Àwọn gómìnà 'yahooyahoo' ní APC ló ń ti Buni láti da ojú ètò ìdìbò adarí ẹgbẹ́ bolẹ̀ - Gómìnà Rotimi Akeredolu
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Ìrírí tí Ilana Omo Oodua àti Sunday Igboho rí lósù mẹ́fà yìí tí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ síi- Ojogbon Banji Akintoye
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa MC Oluomo àti ìdí tí ọ̀pọ̀ ṣe gbàgbọ́ pé alágbára ni
Kini o sẹlẹ nile ejọ́?
Arabinrin Arowojọbẹ jẹ́ ẹjọ́ niwaju Onidajọ Mojisọla Dada ti ile ẹjọ akanṣe ẹṣẹ, iyẹn Special Offences Court to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko.
Nibe lawon agbejoro ti salaye pe inu oṣu kin-ni-in, ọdun ọdun 2019 lọwọ palaba Aishatu segi.
Leyin naa ni ajọ EFCC si fi oju rẹ ba ile ẹjọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu kin-ni-in, ọdun naa.
Ki lo gbe Aishatu Arowojọbẹ di ero ẹwọn?
Owo to le diẹ ni miliọnu meje naira (N7,065,000) ni wọn sọ pe Aishatu lu ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tim Onyeator.
Wọn ni ṣe lo tan ẹni naa lati gba owo yii lọwọ rẹ, pẹlu ọgbọn jibiti lati ba a ra ilẹ ti yoo fi gbin ẹgẹ (paaki), ati pe yoo tun ba a ṣe ọpọlọpọ gaari ninu owo ọhun.
Latigba ti wọn sọ pe Aishatu ti gba owo yii, lo ti na papa bora, ti ẹni naa ko si ri i mọ, idi ree ti wọn ṣe fi ẹjọ rẹ sun ajọ EFCC to ṣe iwadii finnifinni, ko to di pe o fi oju ba ile ẹjọ.
Lẹyin ọpọlọpọ ifojubale ẹjọ, Aishatu gba wi pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn to bẹbẹ fun idariji.
Eyi lo fa a ti Onidajọ Dada fi sọ pe ko lọ ṣe ẹwọn ọdun mẹwaa lati fi jiya ẹṣẹ rẹ.
Ajọ EFCC lo fidi rẹ mule loju opo ayelujara wọn laipẹ yii.























