Tinubu: Ọjà tí kò le kùtà ni mí tẹ bá tì mí lẹ́yìn láti di ààrẹ

Bola Tinubu n bawọn asofin apapọ sọrọ

Oríṣun àwòrán, officialbolatinubu/Instagram

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Aṣiwaju Ahmed Tinubu, to n dije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ APC ti sọ pe laifọtape, ninu gbogbo awọn eeyan to n dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023 bayii, oun nikan lo duro deede.

Tinubu, to ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa nile aṣofin-ṣoju sọrọ ṣalaye pe eeyan o jayopa bi wọn ba sọ pe oun loun pegede figbọrọ jẹka julọ laarin wọn.

Bakan naa ni Tinubu tun lo anfaani ipade to se pẹlu awọn asofin naa lati sọrọ lori iwe ẹri to ni ni fasiti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ awuyewuye lo si ti figbakan ri waye lori boya iwe ẹri asaaju ẹgbẹ oselu APC naa jẹ ojulowo tabi ayederu.

Àkọlé fídíò, Oníṣòwò ọ̀ọ̀nì àti ejò ní ẹran náà ń fún ara lóore láì wo èèwọ̀ àṣà àti ẹ̀sìn tó rọ̀ mọ

First class ni mo mu jade nile ẹkọ fasiti:

Tinubu sọ fun awọn aṣofin apapọ naa pe iwe ẹri onipo kini ni fasiti, iyẹn 'first class' loun ni jade nileewe giga fasiti.

Bakan naa lo tun yan leti awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC naa pe, alaimọ ohun to tọ ni gbogbo awọn to n ba oun du ipo aarẹ fọdun 2023.

" Yatọ si ibeere ati idahun, pupọ awọn to n ba mi dije yii ko ni anfani kankan lati ṣe fun orilẹede Naijiria.

"Emi o wa lati wa yin ara mi o. Mo kan wa lati wa sọ fun yin ni pe mo jẹ ọja ti ko lee kuta fun un yin lati ta.

Emi nikan, ninu awọn oludije wọnyii ni mo jafafa julọ fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023"

Bola Tinubu atawọn asofin apapọ

Oríṣun àwòrán, officialbolatinubu/Instagram

Àwọn tó ń bá mi du ipò ààrẹ ni kò mọ ohun tó kàn fún Nàìjíríà

Ki lesi tawọn aṣofinṣoju fun Tinubu?

Olori awọn ọmọ ileegbimọ aṣofinṣoju to pọ julọ, Honorebu Ado Doguwa fi da Aṣiwaju Tinubu loju pe gbogbo awọn lawọn yoo ṣiṣẹ fun un.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Họnọrebu Doguwa yii kan naa lo ko awọn aṣofin kan lati apa ariwa orilẹede Naijiria sodi wa Tinubu lọ sorilẹede Gẹẹsi, nigba ti ara rẹ ko ya.

Amin iyasọtọ kan

Ọ̀nà ti di fáwọn tó kúndùn láti máa yí èsì ìdìbò - Makinde

Olubadan àti Gómìnà Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Olubadan àti Gómìnà Seyi Makinde

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ní ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò lórí jíjẹ oyè Olubadan sí bí ó ṣe wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Makinde sọ èyí níbi ètò ilé ìjọsìn St. Peters Anglican Church, Aremo, Ibadan láti ṣàmì ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ àṣà Ibadan tí ọdún 2022 tó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá ọdún 2022.

Gómìnà wòye pé bí àwọn kò bá tètè parí aáwọ̀ tó súyọ lórí jíjẹ oyè Olubadan ní kíákíá ó ṣeéṣe kí aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ máa súyọ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹ oyè Olubadan.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ gómìnà Makinde, Taiwo Adisa ní lóòótọ́ ni ó gba àwọn ní àkókò díẹ̀ láti yan Olubadan tuntun bí ó yilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kó gba àwọn ní ọ̀sẹ̀ kan sí méjì lọ.

Ṣùgbọ́n ó ní bí àwọn kò bá paná aáwọ̀ náà kí àwọn tó gbé adé le Olubadan tuntun lórí, Ibadan yóò máa kojú ìpèníjà bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ ìwájú lásìkò tí wọ́n bá jẹ oyè.

Bákan náà ló fi kun pé àtìlẹyìn àwọn ara Ibadan ló ṣokùnfà ní ìpẹ̀tù sí aáwọ̀ ṣe lọ ní ìrọ̀wọ́ rọsẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tẹ̀síwájú pé òun ti ṣe ìlérí fún àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ Ibadan láti má mikàn pé ayẹyẹ náà yóò wáyé pẹ̀lú Olubadan lórí ìtẹ́.

Makinde rọ àwọn ènìyàn láti máa kópa nínú ètò idibò, bí ọ̀nà ṣe pin fún àwọn tó máa ń yí èsì ìdìbò

Gómínà Makinde tún pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti máa kópa níbi ètò òṣèlú, kí wọ́n sì máa dìbò lójúnà àti lè máa yan ẹni tó wù wọ́n sípò olórí, kí wọ́n le lẹ́nu ọ̀rọ̀ tí àwọn olórí kò bá ṣe dáadáa tó.

Ó ní pẹ̀lú òfin tuntun tó wà lórí ètò ìdìbò báyìí, kò sí àyè fún ṣíṣe èèrú èsì ìdìbò, gbogbo ènìyàn ló ní àǹfàní láti mọ bí ó ṣe ń lọ nínú òṣèlú àti pé àìsí níbẹ̀ ni àìbá wọn dási.

Bákan náà ló ní ìgbà tí àwọn kan máa ń kọ èsì ìdìbò tó bá wù wọ́n lórí níbi àkọ́jọ ètò ìdìbò ti di àfìsẹ́yìn tí eégún fi aṣọ.

Bẹ́ẹ̀ ló fi kun pé ayé tí àwọn kan yóò jòkòó sí ibì kan máa kọ èsì ti kọjá, kí oníkálùkù wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí ni báyìí.

Àwọn ará Ibadan gbóríyìn fún gómìnà Makinde lórí oyè Olubadan

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Ààrẹ ọmọ bíbí ìlú Ibadan, Ọmọọba Oluyemisi Adeaga dúpẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Seyi Makinde fún bó ṣe parí aáwọ̀ lóí oyè Olubadan ní tùbí ń nùbí.

Adeaga ní ṣíṣe ètò ìjọsìn náà wáyé láti dúpẹ́ fún Ọlọ́run lórí bí ètò gbígbé ọ̀pá àṣẹ lé Olubadan lọ́wọ́ láìsí ìdíwọ́ kankan.

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀