Ajah-Lagos Mayhem: Ọkọ̀ àjàgbé tẹ ọlọ́kadà àti èrò rẹ̀ pa L'Eko, wàhálà bẹ́ sílẹ̀

Lagos Monitoring Team

Oríṣun àwòrán, @lagospostdotng

Wahala bẹ silẹ lagbegbe iloro Lekki Toll Gate keji, to wa loju ọna marosẹ Lekki-Epe, nipinlẹ Eko, lẹyin ti ọkọ ajagbe kan tẹ ọlọkada kan ati ẹni to gbe pa.

Iroyin ni ijanu ọkọ naa, to n ko yanri, ja ni nnkan bi aago mẹsan an aarọ ọjọ Iṣegun, ko to lọ kọlu ọlọkada naa ati ẹni to gbe.

Lẹyin ijamba naa ni awakọ ọhun fi ọkọ rẹ silẹ to si ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ti ọlọkada naa si ku lẹsẹkẹsẹ, nigba ti ẹni to gbe sẹyin jade laye lẹyin akoko diẹ si.

Oṣojumikoro kan to sọrọ lasiko to n ka ijamba naa silẹ lori ikanni Instagram sọ pe awọn agbofinro wa lagbegbe ọhun nigba ti ijamba a naa ṣẹlẹ amọ wọn ko ṣe ohunkohun ẹmi awọn to faragba ninu rẹ.

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ naa tun ṣoju rẹ sọ pe egungun ọkan lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ fọ lasiko ti ijamba ọhun waye.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo

Rogbodiyan bẹ silẹ, awọn eeyan sun ọkọ ati taya

Ẹwẹ, iku awọn eeyan ọhun da rogbodiyan silẹ lagbegbe naa to bẹẹ ti awọn eeyan ọhun, to fi mọ awọn ọlọkada bẹrẹ ifẹhonuhan lẹsẹkẹsẹ.

Lẹyin naa ni wọn dana sun ọkọ ajagbe ọhun.

Ko tan sibẹ, awọn olufẹhonuhan naa tun fi ina si awọn taya ọkọ loju ọna naa naa, eyii to fa ọpọ sunkẹrẹfakẹrẹ lagbagbe ọhun.

Iroyin ni awọn ọlọpaa ti wọn ran lati pana rogbodiyan naa yinbọn soke lọna ati tu awọn olufẹhonuhan naa ka.

Ẹnikan to wa nibi ifẹhonuhan ọhun, Dr. Smile, sọ fun awọn akọroyin pe lara awọn olufẹhonuhan naa kọlu awọn ọlọpaa nitori pe wọn yinbọn soke.

O ni "Awọn eeyan n binu; wọn n le awọn ọlọpaa sinu ile Eleganza... ṣadede ni awọn ọlọpaa naa de ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn."

"Awọn ọlọpaa ko lẹtọọ lati yinbọn ni iru akoko bayii."

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu sọ pe awọn oṣiṣẹ awọn ko lo ipa to le lati pana wahala naa.

O ni "Kọmiṣọna ni ki awọn oṣiṣẹ wa lọ pana rogbodiyan naa, wọn si ti ṣe bẹẹ."

"A ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa... a ko lo ipa to le lati tu awọn olufẹhonuhan naa ka amọ wọn ti ọwọ ipa bọ ọrọ naa."

Nigba to n sọrọ, agbẹnusọ igbimọ amuṣẹya ipinlẹ Eko, Gbadeyan Abdulraheem ni "Awọn ti ọrọ naa sọju wọn sọ pe 'one way' ti ọlọkada naa gba lo bi ijamba naa, bi beẹ kọ, iṣẹlẹ naa ki ba ma ti waye."

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀