MC Oluomo: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko kìlọ̀ fún NURTW lórí ìwọ́de tí wọ́n ń múra rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW pe oun ko ni fi aaye gba ẹgbẹ naa lati ṣe ifẹhonuhan kankan nipinlẹ ọhun.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi lo fi ikilọ ọhun lede lẹyin iroyin to n lọ laarin igboro pe awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW n mura lati ṣe iwọde lonii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022.
Ikede ifẹhonuhan naa to n tan kalẹ lori ayelujara sọ pe awọn agbegbe bii Ilupeju, Oshodi, Mushin, Mile 12, Ajah ati Lagos Island ni iwọde naa yoo ti milẹ titi julọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀pọ̀ òkú ń sùn ní Ukraine, wọ́n ń sin wọ́n ní àsinpọ̀ sí ibojì kan ṣoṣo
- Ìwà àtakò sí ìjọba ní bí ọlọ́pàá bá da iṣẹ́ sílẹ̀, kò tọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Afurasí Fulani gé ọwọ́ Fijilańté méjèèjì ni Iwere Ile ni Ipinle Oyo
- Ẹ wo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire
- Ohun tó fa wàhálà Hijab ní Ijagbo rèé - Olùkọ́ àgbà
- Ẹ gbà mi o, àwọn oníjìbìtì ayélujára ti ń bèèrè ìrànwọ́ lórúkọ́ mi - Kemi Afolabi lọgun
- "Ẹgbẹ́ àjẹ́ tí mo wà ní Anambra ló ní kí n pa ọmọ ọ̀gá mi l'Eko"
- Ipò tí Naijiria wà fi hàn pé inú Ọlọrun kò dùn sí orílẹ̀-èdè yìí - Gani Adams
- Ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo la orí mọ́ táísì, mo sì fẹ́ ẹ̀ pàdánù ọpọlọ nígbà tà ń ya fíìmù - Mide Martins
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ afurasí 11 tó dáná sun ọba nílú Agodo
Wayii o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti wa fi ọkan awọn olugbe ipinlẹ naa balẹ pe awọn agbofinro ti ṣe awọn eto to yẹ lati daabo bo wọn lọwọ awọn kọlọrọsi to ba n mura lati da igboro ru.
Kọmiṣọna ọlọpaa sọrọ lẹyin ti wọn kẹfin erongba awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW lati ifẹhonuhan lori rogbodiyan to n waye ninu ẹgbẹ ọhun.
Ki ni rogbodiyan to n waye ninu ẹgbẹ NURTW ipinlẹ Eko?
Ṣaaju ni awọn adari ẹgbẹ naa ti kọkọ jawe lọ rọkun nile fun alaga ọhun nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo.
Wọn kede igbesẹ naa lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii ninu atẹjade kan ti akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Kabiru Yau buwọlu.
Ẹsun ti wọn fi kan MC Oluomo ni pe ko bọwọ fun ofin atawọn adari ẹgbẹ naa, wiwu iwa ibajẹ gẹgẹ bii olori ẹgbẹ, to fi mọ igbimọ lati da wahala silẹ laarin ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Eko.
Amọ lọna ati pana wahala to le waye lẹyin ti wọn ni ki Olumo lọ rọkun nile, ijọba ipinlẹ Eko fofin de iṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ ọhun, paapaa lawọn ibudokọ.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa, amọ ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ fun awọn akọroyin pe gbogbo ẹgbẹ lo ni ofin tirẹ, amọ ko bojumu ki ẹnikan ṣoṣo maa gbe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni to ju apapọ ẹgbẹ lọ.
Ẹwẹ, awọn anowye ohun to lọ kan ti sọ oe gbogbo rogbodiyan naa lọwọ oṣelu ninu, ati pe gbogbo ẹ ko ṣẹyin ididbo to n bọ lọdun 2023.




















