Hunters kill lion in Borno: Àwọn ọdẹ pa kìnìún kó má báà ṣe àwọn ará ìlú léṣe.

Oríṣun àwòrán, News Agency of Nigeria NAN
Adarí ẹka Igbó-ọba àti ẹranko igbó tó tun ń rí sí ètò àyíká ní ìpínlẹ̀ Borno, Peter Ayuba ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́dẹ pa kìnìún kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Konduga ní ìpínlẹ náà.
Ayuba tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Maiduguri ní lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn ọdẹ náà pa Kìnìún náà.
Ó ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ní ọgbà àwọn ẹranko igbó nilẹ̀ Cameroon, ni kìnìún náà ti ṣìnà wọ ìlú náà.
- Kiniun pa olusọ ọgba ẹranko
- Leon van Biljon dí èrò ọrun nípasẹ̀ Kìnìún rẹ̀
- Wo àwọn kìnìún tó ń ṣe ọ̀fìnkìn lẹ́yìn tí wọ́n kó covid-19 lára àwọn èèyàn
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Kìnìún mẹ́rìnlá bọ́ sígboro
- Kí ló lè mú ìjọba pàṣẹ pé kí wọ́n ka gbogbo ẹranko igbó àti ẹja inú omi?
Bákan náà ló ní àwọn erin ti ya wọ àwọn ìlú kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Kala-Balge láìpẹ́ yìí àti pé àwọn ìkokò pa ọkùnrin kan nínú igbó kan nínú ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaga.
Ayuba ṣàlàyé pé nítorí tí ọ̀pọ̀ ìlú ti di aharo, àwọn ẹranko ti ń ya wọ ìlú.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ààrin gbùngbùn ìlú ni kò sí èèyàn nínú rẹ̀ mọ̀ látàrí ogun Boko Haram tó jẹ́ àwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń padà síbẹ̀ nígbà tí àláfíà ti ń jọba báyìí.
Ó wá rọ àwọn ará ìlú náà láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nítorí àwọn ẹranko igbó mìíràn ṣì le wà ní agbègbè náà.
Kìnìún náà lé àwọn ará ìlú kí àwọn ọdẹ tó pa á
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, agbẹnusọ ìjọba ìbíll náà, Asheikh Chabbol ní kìnìún náà lé àwọn àgbẹ̀ kan ní ìlú Malari kí wọ́n tó pe àwọn ọlọ́dẹ láti báwọn pá.
Chabbol ní àwọn ọdẹ méjì ló farapa nígbà tí wọ́n wọ ìjàkadì pẹ̀lú kìnìún kó tó di pé wọ́n ri pa.
Ó ní àwọn ọdẹ tó farapa ọ̀hún ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ tí àwọn sì ti gbé òkú kìnìún náà fún ilé iṣk tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká.

















