Timothy Adegoke: Onímọ̀ ìwádìí ní egungun itan ọ̀tún olóògbé ti rún nígbà táwọn ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀

Onímọ̀ ìwádìí, Waheed Akanni Oluogun tii se ẹlẹri kẹrin, tun tẹsiwaju nipa ijẹri rẹ lórí ohun tí ó ṣokùnfà ikú Timothy Adegoke.
Oluogun ní ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fi abẹ dá ọgbẹ́ sí olóògbé náà lára kí ẹ̀mí tó bá lára rẹ̀.
Oluogun tó jẹ́ àgbà onímọ̀ ìwádìí ní ilé ìwòsàn ìkọ́ni ìlú Osogbo, ní àyẹ̀wò òkú olóògbé náà lo ṣàfihàn pé ojú ọgbẹ́ tuntun wà níbi ẹ̀gbẹ́ òsì àyà rẹ̀, tó sún mọ́ ibi abíyá.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀jẹ̀ àpọ̀jù tó dà lára Timothy Adegoke torí ọgbẹ́ tó ni ló ṣekú pà á - Onímọ̀ ìwádìí
- Ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́rin tó gé orí Sofiat Okeowo láti fi ṣẹ́ṣó gba ìtúsílẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní àwọn awakọ̀ èrò fẹ́ ṣe ìwọ́de lónìí l‘Eko torí yíyọ MC Oluomo nípò?
- Kí ló fa rògbòdìyàn tó gbòde ní Ajah, tí ẹ̀mí méjì fi bọ́, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bájẹ́?
- "Sylvester Oromoni tọ̀ mí wá pé itan ń ro òun kó tó kú, mo sì ba fi ọwọ́ ra á pẹ̀lú òògùn ara ríro"
- Ìwà àtakò sí ìjọba ní bí ọlọ́pàá bá da iṣẹ́ sílẹ̀, kò tọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Kò pọn dandan fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láti lo hijab nílé ẹ̀kọ́ - Ilé ẹjọ́
Bákan náà ló ní àyẹ̀wò náà fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ dì sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àyà rẹ̀ èyí tó túmọ̀ sí pé àpọ̀jù ẹ̀jẹ̀ látara ọgbẹ́ náà ló sẹ okùnfà ikú rẹ̀.
Egungun itan ọ̀tún ti rún nigba ta se ayẹwo oku Timothy Adegoke - Oluogun
Ó tún tẹ̀síwájú pé kò sí ẹ̀jẹ̀ níbi ọrùn àti pé ọkàn rẹ̀, ọpọlọ, ẹ̀dọ̀ àti kídìnrín rẹ̀ wà bó ṣe yẹ ṣùgbọ́n tí wọ́n tí ń jẹrà.
Àmọ́ ó fi kun pé ará òkú tó ti ń jẹrà kò ní kí ìwádìí má fi ohun tó fa ikú hàn.
Oluogun tún ṣàlàyé pé àbájáde ayẹwo ẹya ara X-ray fi hàn pé egungun itan rẹ̀ ọ̀tún ti rún, tí egungun ọwọ́ rẹ̀ òsì sì ti yẹ̀ kúrò bó ṣe yẹ kó wà.
Báwo ni ìwádìí ṣe bẹ̀rẹ̀?
Oluogun sọ fún ilé ẹjọ́ pé ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kọkànlá ọdún 2021 ni ọlọ́pàá pe òun láti wá hú òkú Timothy Adegoke.
Ó ní ní òpópónà Ile Ife sí Ede ní ibojì tí wọ́n sin Timothy Adegoke sí ni àwọn ti hú òkú náà níṣojú àwọn ọlọ́pàá àti àwọn mọ̀lẹ́bí Adegoke.
Ó ṣàlàyé pé àwọn bá òkú rẹ̀ ní dídì.
"Wọ́n fi aṣọ ìbora ilé ìtura wé e ní gbogbo ara láì ṣẹ́ ibì kan kù tí wọ́n fi okùn méjì dìí, ọ̀kan níbi ọrùn, ìkejì níbi kókó ẹsẹ̀."
Ìdin ti ń yọ níbi orí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì títí dé ibi ọwọ́ rẹ̀.
Bákan náà ní àwọn onímọ̀ ìwádìí méje ni àwọn ṣe àyẹ̀wò lórí òkú náà lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù kọkànlá, ọdún 2021.

Ẹ̀jẹ̀ àpọ̀jù tó dà lára Timothy Adegoke torí ọgbẹ́ tó ni ló ṣekú pà á - Onímọ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke and Rahmon Adedoyin/Facebook
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbẹjọ tun tẹsiwaju lọjọru nile ẹjọ giga ilu Osogbo nibi ti igbẹjọ ti n waye lati mọ iru iku to pa Timothy Adegoke.
Adegoke ni akẹkọọgboye keji nile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife amọ to ku sile itura Hiton lasiko to sun mọju sibẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, awọn ẹlẹri ti bẹrẹ si ni bọ sinu igi lati jẹri nile ẹjọ nipa ohun ti wọn mọ lori iku oloogbe naa lasiko igbẹjọ to waye ni ọsẹ.
- Timothy Adegoke: Raheem Adedoyin ní káwọn òṣìṣẹ́ Hòtẹ́ẹ̀lì òun fi Bíbélì búra pé wọ́n ò ní tú àṣírí
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Timothy Adegoke: Ìyàwó Timothy Adegoke jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́, gbọ́ nípa ìjà tó jà fún ọkọ̀ rẹ̀
- Ilé ẹjọ́ fi Rahman Adedoyin pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe bẹ̀rẹ̀ l'Osun
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
Lonii ọjọru ti igbẹjọ naa tun waye, onímọ̀ ìṣègùn náà tó jẹ́ àgbà dókítà ní ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ isegun to wa ni ìlú Osogbo, Dokita Waheed Akanni Oluogun sọrọ nipa abọ rẹ lori ohun tó ṣè okùnfà ikú Timothy Adegoke.
Apa osi Timothy Adegoke ti yọ kuro ni ara rẹ nigba ta ri oku rẹ:
Nigba to n salaye abọ ayẹwo iwadii iku to pa Timothy niwaju adajọ, Oluogun ni iwadii oun ṣàfihàn pé ẹ̀jẹ̀ àpọ̀jù ló ń dà ní ara Timothy Adegoke nitori ọgbẹ to ni eyi to se okunfa iku rẹ naa.
Dokita naa ní apá òsì Timothy Adegoke ni wọ́n ti yọ kúrò nínú ara rẹ̀ nígbà tí àwọn yóò fi hú òkú rẹ̀.
Ó ní aṣọ pupa ní àti ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti aṣọ ìbora ilé ìtura ní àwọn ba ni ara rẹ̀.
Egbo wa lara Timothy Adegoke lasiko ayẹwo oku rẹ:
Onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó tó wá jẹ́rìí lórí ohun tí ó ṣokùnfà ikú Timothy Adegoke ní egbò wà lára olóògbé náà nígbà tí àwọn ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀.
Bákan náà ló fi kun pé àyẹ̀wò fi hàn pé ṣáká ni ara olóògbé náà dá kí ó tó di pé o jẹ́ Ọlọ́run nípè léyìí tó túmọ̀ sí pé kò sí àìsàn kankan tó ń bá a fínra kó tó kú.
Onímọ̀ ìṣègùn náà tẹ̀síwájú wí pé àwọn tíṣù tí àwọn yọ níbi egbò tó wà ní ara òkú Timothy Adegoke fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ ń jáde síbẹ̀ láti ara egbò náà
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ìgúnpá Timothy Adegoke ti yọ kúrò ní ara rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi hú òkú rẹ̀ fún àyẹ̀wò.
Bi Rahmon Adedoyin se de sile ẹjọ lonii ree:
Rahmon Adedoyin lo de sile ẹjọ giga ipinlẹ Osun laarin awọn ẹsọ alaabo nla to lagbara.
Adedoyin ni wọn gbe wa sile ẹjọ naa pẹlu awọn ẹlẹri mẹfa miran ti orukọ wọn n jẹ Madgalene Chiefuna ati Adedeji Adesola.
Awọn yoku ni Adeniyi Aderogba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem and Kunle Adebayo.
Ki lo waye lasiko igbẹjọ to gbẹyin:
Ni ọjọ Ẹti, ọkọ kọkanla osu kẹta ti igbẹjọ waye kẹyin lori iku Timothy Adegoke, lara awọn to jẹri nile ẹjọ naa ni ọga ọlọpaa insipẹkitọ Olaniyan Afeez.
Oun si ni ẹlẹrii kẹta ti yoo sọrọ lori ohun ti wọn mọ nipa iku oloogbe naa.
Olaniyan Azeez si lo jẹri niwájú Adajọ Adepele Ojo ti ilé ejò gíga ipinlẹ Osun lórí bí wọ́n ṣe rí òkú Timothy Adegoke lẹyin tí àwọn mọlẹbi pé akiyesi ilé iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Osun si isẹlẹ naa.
Ọga Ọlọpa náà salaye ohun ti ọ̀kàn lára àwọn afurasí ninu ẹjọ naa, ti orukọ rẹ n jẹ Adeniyi Aderogba, sọ nígba tí wọn gba ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ silẹ.
O ni Aderogba sọ pe lẹyin ti wọn rí òkú Timothy Adegoke nínú yàrá room 305, ni ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ramoni Adedoyin sọ pé kí àwọn fi Bíbélì bura pe awo isẹlẹ naa ko ni ya.
Olaniyan ni iwadii awọn fihan pe Aderogba yii lo yi ìwé akọsilẹ orukọ awọn alejo to sun sile itura náà padà, tí ó sì yọ orúkọ Timothy Adegoke kúrò lára àwọn tó wà sì ilé itura ọhun.
Igbẹjọ naa si n tẹsiwaju lonii, bo wa si se n waye, ni BBC Yoruba yoo maa fi isẹlẹ naa to yin leti.





















