Timothy Adegoke: Ìjọba àpapọ̀ ní òun jámi lórí ẹjọ́ tí òun ń bá Adedoyin àti awọn afurasí mẹ́sàn-án míràn ṣe

Oríṣun àwòrán, Rahmon Adedoyin and Timothy Adegoke/Facebook
Ijọba apapọ ti kede pe oun ti yọwọ yọsẹ kuro lori ẹjọ toun n ba awọn afurasi mẹwa ti wọn fi ẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku Timothy Adegoke se.
Adegoke lo ku sile itura kan nilu Ile Ife nipinlẹ Osun, ti ijọba apapọ si ti n ba ẹni to ni ile itura naa, Rahmon Adedoyin ati awọn eeyan mẹsan-an miran se ẹjọ lori iku oloogbe naa.
Ikede naa lo bọ sọwọ awọn akọroyin lonii ti igbẹjọ Timothy Adegoke n waye nile ẹjọ giga ti ijọba apapọ nilu Abuja.
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
Ki lo de ti ijọba fi yọwọ ninu igbẹjọ iku Adegoke:
Atẹjade kan ti ile ẹjọ giga tijọba apapọ nilu Abuja fisita lo kede pe ijọba apapọ ti yọwọ ninu ẹjọ naa.
Atẹjade ọhun ti awọn agbẹjọro fun ijọba, Ochogwu Ogbeh ati Sidi Abdulrashid Isyaku fọwọsi ni ọjọ Aje, ọjọ Keje osu Keji ọdun 2022 lo sisọ loju ọrọ naa.
Bi o tilẹ jẹ pe atẹjade naa ko salaye pupọ lori idi ti ijọba ko fi bawọn afurasi naa se ẹjọ mọ amọ o ni ki iwadi le tẹsiwaju ni oun fi yọwọ yọsẹ lori ẹjọ yii.
Awọn wo ni afurasi ti igbẹjọ iku Adegoke kan:
Awọn afurasi olujẹjọ ti ẹsun naa kan ni ẹni to ni ile itura Hilton to wa nilu Ile Ife ti Timothy Adegoke ku si, eyiun Ọmọọba Rahmon Adedoyin, tii se ẹni ọdun mẹrinlelọgọta.
Awọn yoku ni arabinrin Adedeji Adesola, ẹni ọdun mtalelogun, Magdalene Chiefuna, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Adeniyi Aderogba, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
Awọn yoku ni Oluwale Lawrence, ẹni ọdun mẹtadinlogoji bakan naa ati Oyetunde Kazeem, ẹni ọdun mejidinlogoji.
Adebayo Adekunle tii se ẹni ọdun marundinlogoji naa wa lara awọn afurasi ọhun ati ọmọbaa Raheem Adedoyin to ti na papa bora bayii.
Ọrọ naa si tun kan Esther Asigoh toun naa ti na papa bora ati Quadiri Moshood ti oun naa ti sa lọ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, High Court Abuja
Adajọ kede pe ki wọn maa gbe ẹjọ iku Adegoke pada sipinlẹ Osun:
Wayi o, Ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to kalẹ si Gudu nilu Abuja ti pasẹ pe ki wọn gbe ẹjọ iku Timothy Adegoke pada wa si Osogbo.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju pe agbẹjọro tuntun to tẹwọgba ẹjọ naa, Agba amofin Femi Falana lo ti kọwe beere pe ki wọn gbe ẹjọ naa si ipinlẹ Osun.
Falana ni ipinlẹ Osun ni isẹlẹ ẹsun ipaniyan naa ti waye, nitori naa, ipinlẹ Osun lo yẹ ki wọn ti gbọ ẹjọ naa, kii se ilu Abuja ti igbẹjọ ti n waye.
Ki lo sẹlẹ nibi igbẹjọ to waye loni:
Bi akoko igbẹjọ se to ni aarọ oni ọjọ Isẹgun, ni wọn gbe asaaju olujẹjọ, Rahmon Adedoyin ati awọn olujẹjọ yoku de sile ẹjọ.
Ni kete to de sile ẹjọ laarọ oni, ni adajọ to n gbọ ẹjọ naa kede pe wọn gbe igbẹjọ naa pada si ipinlẹ Osun nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Adajọ naa ni ẹka eto idajọ ti gba iwe lati ọdọ agbẹjọro to n duro fun mọlẹbi oloogbe pe ki wọn gbe ẹjọ naa pada si ipinlẹ Osun.
Iṣẹlẹ isekupani Timothy Adegoke se waye ni Ile Ife:
Ọjọ karun un oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Adegoke rinrin ajo lati Abuja lọ si Ile Ife lati ṣe idanwo MBA ni fasiti OAU.
Ile itura Hilton hotel ni a gbọ pe o wa ki o to di pe o kan ṣadeedee di awati.
Lẹyin ọ rẹyin, oku Timothy ni wọn pada ri.
Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa mu oludasilẹ ile itura Hilton hotel, Ramon Adedoyin at'awọn afurasi mẹfa mii.
Ileeṣẹ ọlọpaa gbe wọn lọ sile ẹjọ niluu Abuja lori ẹsun pe wọn lọwọ si iku Adegoke.





















