Timothy Adegoke: Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jọ́ lórí ikú àbúrò mi ni Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì rán lawyer kó gbé owó wá - Ẹ̀gbọ́n Timothy

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Lori awuyewuye to n tan kaakiri pe oludari ile itura ti akẹkọọ ipele Masters ni fasiti Obafemi Awolowo ti Ile Ife, Timothy Adegoke ku si ti n fi owo lọ awọn mọlẹbi Timothy pe ki wọn le dakẹ lori ṣiṣe ẹjọ, ẹgbọn oloogbe ti ba BBC Yoruba sọrọ lori rẹ.

Ẹgbọn Timothy Adegoke to ku si ile itura kan to lọ duro si ni Ile Ife lati le lọ kọ idanwo rẹ ni Fasiti OAU, Adegbade Adegoke sọ fun BBC Yoruba pe ni gbogbo igba ti awọn fi n wa aburo oun to wọ ọkọ baalu lọ si Akure lati Ife ni awọn to lọwọ ninu ẹ ko kọkọ fẹ jẹwọ afigba ti awọn tọpinpin.

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Adegoke

O ṣalaye bi wọn ṣe kan si banki Timothy ti wọn si sọ fun wọn pe lootọ lo fi owo ranṣẹ si eeyan meji to si jẹ oṣiṣẹ hotẹẹli naa.

O ni oun mọ eeyan kan lara wọn, oun si ni wọn fun ogun mọ.

"O kọkọ ni lootọ ni ẹni yẹn wa, to si fi owo ranṣẹ amọ awọn ko tii rii ko wa si ile itura".

Igba ti wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ sii lọwọ lo to jẹwọ to tun darukọ gbogbo awọn to pa Adegoke ti wọn si lọ sin in.

Adegbade ṣalaye pe obinrin oṣoṣẹ kan to maa n fi ẹda fọto akọsilẹ to ba ṣe sori foonu ara rẹ ki wọn ma baa parọ mọ lo tu aṣiri to jẹwọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ pe lootọ ni o Timothy wa sile itura awọn ti wọn si paa.

Ẹgbọn Adedoyin

"Koda wọn ni ọga awọn Adedoyin mọ si gbogbo ẹ amọ to kilọ fun awọn lati ma sọ ohunkohun".

"Wọn sọ fun wa pe ọmọ Adedoyin gangan lo dari awọn ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ lọ pa Timothy ti wọn si sin in".

Adegbade gbagbọ pe ẹjọ yii ti di ti agbaye bayii ti wọn si sọ fun un pe wọn gbe ẹjọ naa lọ si Abuja bayii tori ọga agba awọn ọlọpaa sọ pe oun nifẹ si ẹjọ naa.