Timothy Adegoke: Ọlọ́pàá Osun ṣàlàyé ohun tó ń ṣèdíwọ́ lórí ìgbẹ́jọ́ ikú akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU

Rahmon Adedoyin ati Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Rahmon Adedoyin and Timothy Adegoke

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti wọn ko fi ti pe arakunrin Raheem Adedoyin lẹjọ lori ẹsun pe o mọ si iku akẹkọọ fasiti OAU to ku nile itura baba rẹ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun Yemisi Opalola lo salaye ọrọ yii lọjọbọ.

Adedoyin ni oludari ile itura Hiltons Hotels and Resorts, Ile-Ife to jẹ ti baba rẹ Ramon Adedoyin.

Idahun ati alaye yii lati ọdọ ọlọpaa naa lo n waye lẹyin ti agbẹjọro awọn mọlẹbi ti ọmọ wọn poora, Kayode Ajulo n beere alaye lati maa beere idi tọrọ fi ri bẹẹ.

Opalola ninu esi to fọ fún pada sọ pe, idi ti awọn ṣi fi n wo Raheem niran ni pe esi ayẹwo oku Timothy Adegoke ko tii jade.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

Opalola tun sọ pe ni ahamọ lọdọ awọn ṣi ni Ramon Adedoyin, tii se baba to ni ile itura naa gan-an wa ati pe awọn ko ti pe lẹjọ nitori esi ayẹwo yii ti ko tii jade.

Agbẹjọro mọlẹbi oloogbe naa Kayode Ajulo, lo ti kọkọ fi aidunnu rẹ han lori bi ileesẹ ọlọpaa ko ṣe ti kede Raheem, to jẹ oludari ile itura naa gẹgẹ bi afurasi, lẹyin tí ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ile itura naa jẹwo pe oun lo ṣeto bi wọn ṣe gbe oku lọ ju si inu igbo.

Agbẹjoro naa tun sọ pe o jẹ kayeefi pe won ko ti pe ẹni to ni ile itura naa lẹjọ.

O ti to ọjọ mẹta ti BBC Yoruba ti n jabọ lori iṣẹlẹ iku arakunrin Timothy Adegoke, ti wọn rí oku rẹ ninu igbo ni Ile Ife.

Akẹkoo OAU Ife ni Timothy, ile itura Hilton to de si ni wọn ti ri gbẹyin, ko to di pe wọn ba oku rẹ ninu igbo.

Orisirisi alaye lo ti gbòde kan lori bi o ti ṣe ku ṣugbọn ileesẹ ọlọpaa ni eyi tó lè jẹ atọna si isẹlẹ ni ki awọn mọ nkan ti ayẹwo oku, 'autopsy' ba gbe jade.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí