Sylvester Oromoni: Nọ́ọ̀sì tó ń ṣiṣẹ́ ní Dowen College jẹ́rìí nílé ẹjọ́ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ náà

Im allege say im son tok say na some five boys bin enta im room, put off light and beat am up in di presence of oda students.

Nọọsi kan to jẹ oṣiṣẹ nile ẹkọ Dowen College, Omobola Kayode, ti jẹri niwaju adajọ lori iku akẹkọọ ile ẹkọ naa, Sylvester Oromoni.

Omobola to kẹkọọ gboye lorilẹ-ede Ukraine bẹrẹ isẹ nile ẹkọ ọhun ninu oṣu kankọla, ọdun 2021.

Gẹgẹ bii ohun ti nọọsi naa sọ, Oromoni wa si ọdọ awọn nile iwosan ile ẹkọ naa lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 pẹlu ọrẹ rẹ kan, to si sọ pe itan n ro oun.

O ni lẹyin eyii ni dokita ile ẹkọ naa ni ki oun ba a fi ọwọ pa itan naa, oun si tun fun ni oogun Paracetamol, lẹyin naa lo sun lọ.

Amọ lẹyin ti wọn yoo gbe Sulvester kuro nile iwosan naa, n ṣe lo n tẹpa rin.

Àkọlé fídíò, Oníṣòwò ọ̀ọ̀nì àti ejò ní ẹran náà ń fún ara lóore láì wo èèwọ̀ àṣà àti ẹ̀sìn tó rọ̀ mọ

Nọọsi ọhun sọ pe wọn ko bun oun gbọ pe oloogbe naa ṣeṣe lasiko to n gba bọọlu alafẹsẹgba ṣaaju iku rẹ.

O ni "Ko ṣaarẹ lasiko to wa si ọdọ wa, oun pẹlu ọrẹ rẹ kan ni wọn si jọ wa."

"O sọ pe oun fẹ mu bibeli kan nilẹ amọ itan n ro ni ẹsẹ ọtun."

"Mo ba fi ọwọ pa itan ọhun, lẹyin naa ni mo fun ni oogun Paracetamol ati oogun ara riro mii."

Nigba ti agbẹjọro idile Oromoni beere lọwọ Omobola, ẹni to fun laṣẹ lati ni ki akẹkọọ naa maa lọ sile, o ni alaṣẹ ile ẹkọ naa ni.

Omobola sọ pe ilera oloogbe ọhun ko tii buru to bẹẹ lasiko to wa si ile iwosan, ti oun si ṣe itọju rẹ.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro ijọba ati agbẹjọro idile Oromoni, adajọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun ati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo

Ki ni ọlọpaa sọ ṣaaju?

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ ninu oṣu Kinni, ọdun yii pe ko si ẹri to daju lati fidi rẹ mulẹ pe, awọn kan lo lu akẹkọọ ile ẹkọ Dowen ni Lekki, Sylvester Oroomoni ki ẹmi to bọ lẹnu rẹ.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko tẹlẹ, Hakeem Odumosu ṣalaye fawọn akọroyin e ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe wọn fipa fun Sylvester ni kẹmika mu ki o to ku.

Odumosu ni esi ayẹwo oku ti wọn ṣe lara oku Sylvester fihan pe iku ati ọdọ Ọlọrun wa ni akẹkọọ ọmọ ọdun mejila naa ku.

Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe ko si ẹri bakan naa lati fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹgbẹ Sylvester kan fẹ fi ipa mu wọ ẹgbẹ okunkun bakan naa.

Ọgbọnjọ oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Sylvester ku lọna to ya ọpọ eeyan lẹnu.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè i