Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Àkọlé fídíò, Anifat Bello: Mọ́tò gbá mi lẹ́nu iṣẹ́, eyin méjì fòyọ àmọ́ mo fi eyín oníke rọ́pò rẹ̀

Kii se ohun tuntun pe awọn obinrin n sisẹ ọlọpaa tabi dari ọkọ loju popo, ti wọn si n sisẹ naa daradara bo se yẹ.

Bakan naa, ọpọ igba la ti maa n ri awọn ọlọpaa adari ọkọ loju popo ti wọn maa n da ara gidi lati pe akiyesi araalu si isẹ takuntakun ti wọn n se.

Ọpọ ninu wọn lo ti gba ami ẹyẹ lati ọdọ ijọba ipinlẹ ti wọn ti n sisẹ, tawọn araalu naa si maa n mọ riri wọn.

Irufẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo bẹẹ ni Anifatu Bello, to n dari ọkọ lagbegbe Mortuary nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.

Anifatu, ti awọn ololufẹ rẹ tun maa n pe ni iya Ibeji, lo salaye fun BBC Yoruba pe kii kuku se pe oun bi ibeji lootọ, wọn kan wa orukọ naa fun oun ni.

Bawo ni Anifatu Bello se bẹrẹ isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori irinajo rẹ lẹnu isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo, Anifatu ni osu kẹwa ọdun 1991 ni oun bẹrẹ isẹ naa.

O si ti lo ọdun mọkanlelọgbọn lẹnu isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo bayii.

Anifatu, tii se ọmọ bibi ilu Idowa nipinlẹ Ogun ni isẹ ọlọpaa gangan lo wu oun lati se amọ wọn sọ fun oun nile ẹkọ awọn ọlọpaa pe oun ko ga to.

O ni idi ree ti oun se gba lati sisẹ ọlọpaa keji tii se isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo.

O salaye pe ọdun 1996 si 1998 ni oun kọkọ bẹrẹ isẹ naa nilu Abeokuta, ti oun si foju wina ọpọ isoro lẹnu isẹ naa.

Mọto ti gba mi ri, ti mo si tun maa n koju iwa titabuku ẹnu lẹnu isẹ:

Nigba to n sọrọ lori awọn ipenija to ti koju rẹ lati igba to ti bẹrẹ isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo, Anifatu ni ẹnu ko gba iroyin.

“Ọkọ ti gba mi ri loju popo ninu osu keji ọdun 1998, ti eyin meji si yọ lẹnu mi amọ mo ti fi eyin onike rọpo rẹ.

Bakan naa ni mo ti koju iwa ọyaju ati sise abuku si mi loju popo amọ ọga ọlọpaa atawọn araalu dide lati gbe mi nija.

Wọn gbe ẹni naa lọ sile ẹjọ, ti adajọ si da lẹbi.

Bakan naa, ọkunrin kan yaju si mi ni Iyana Mortuary amọ awọn araalu gbe ija mi, ti wọn si da ọkunrin naa lẹbi.

Mo gba ami ẹyẹ ati owo latọdọ ẹgbẹ alaanu lati se iwuri fun mi:

Anifatu tun mẹnuba awọn anfaani to ti jẹ lẹnu isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo.

To si ni lara awọn ọjọ manigbagbe oun lẹnu isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo ni bi ẹgbẹ alaanu Rotary se fun oun ni ami ẹyẹ.

Bakan naa lo ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa da owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹjọ naira (N150,000) jọ fun oun lọjọ ami ẹyẹ naa.

“Mo sọkun ayọ lọjọ ti ẹgbẹ Rotary sadede pe mi, ti wọn si fun mi ni ami ẹyẹ pe mo dangajia lẹnu isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo.

Omije bọ loju mi nitori ami ẹyẹ ati owo 150,000 ti wọn tun da jọ fun mi.

Bi o tilẹ jẹ pe kii se pe owo naa pọ pupọ amọ pe wọn tiẹ ranti mi, ti wọn si mọ riri isẹ ti mo n se, lo n pa mi lẹkun.”

Anifatu wa parọwa si awọn akẹẹgbẹ rẹ, ti wọn jọ n se isẹ ọlọpaa adari ọkọ loju popo lati maa fi ayọ sisẹ wọn.

Isẹ to n daabo bo ẹmi la n se, o si yẹ ka maa gbe ironu wa sile, ka si maa gbe ayọ wa sibi isẹ.”