Lagos VIO - Ǹjẹ́ o mọ ìyàtọ̀ ojúṣe ọlọ́pàá, VIO, FRSC àti LASTMA lójú pópó?

Osisẹ VIO mu awakọ kan

Oríṣun àwòrán, @ElgivaStephen

Ileeṣẹ to n ṣe ayẹwo ọkọ nipinlẹ Eko, VIO ti sọ pe lẹyin ọlọpaa, oun nikan lofin orilẹede Naijiria ati ti ipinlẹ Eko fun laṣẹ, lati da ọkọ duro fun ayẹwo loju popo laisi pe irufẹ ọkọ bẹẹ ṣẹ ṣaaju.

Ọga agba ileeṣẹ VIO ni ipinlẹ Eko, Abdulafeez Toriọla lo sọ eyi di mimọ, lasiko to n kopa lori eto ifọrọwanilẹnuwo ori ikanni ayelujara ileeṣẹ BBC News Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Toriọla ni, ko si idarudapọ laarin iṣẹ ọlọpaa, VIO, ẹṣọ oju popo FRSC, LASTMA atawọn ajọ agbofinro oju popo miran kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa julọ ni ipinlẹ Eko.

O ni fun apẹẹrẹ, LASTMA ko lee ṣadede da ọkọ duro bi ọkọ ko ba ṣẹ, bakan naa pẹlu awọn ẹṣọ oju popo FRSC.

Oju popo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, @followlastma

"VIO nikan lo lee da mọto duro lati beere awọn nnkan bii iwe ọkọ ati boya mọto dangajia tabi ko dangajia. Nipasẹ abala ofin irinna ọkọ Section 12 subsection 2 iwe ofin Naijiria."

O ni ṣugbọn gbogbo awọn ajọ agbofinro wọnyii lo lee da ọkọ duro loju popo, ṣugbọn idi ti olukaluku lee fi da ọkọ duro lo yatọ, to si ju ara wọn lọ.

Ọga agba ileeṣẹ VIO ni ipinlẹ Eko, Abdulafeez Toriọla
Àkọlé àwòrán, VIO ni ko si idarudapọ lori ojuṣe ọkọọkan awọn ajọ aggbofinro loju popo nipinlẹ Eko tabi ni ibikibi lorilẹede Naijiria.

Ọga agba ileeṣẹ VIO nipinlẹ Eko ọhun wa ke sawọn ọlọkọ, lati kun ijọba lọwọ lọna ati wagbo dẹkun si ọwọja ayederu iwe ọkọ lorilẹede Naijiria.

O ni awọn ọlọkọ gbọdọ rii daju pe ileeṣẹ VIO ni wọn ti n gba iwe wọn funrawọn.

Oju popo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, @followlastma

O ni ileeṣẹ VIO nipinlẹ Eko ti ni awọn ohun elo igbalode, lati fi ṣe ayẹwo iwe ọkọ lati mọ ayederu yatọ si ojulowo.

Bakan naa lo ṣalaye pe, ko si eeyan to kọja ofin irinna lorilẹede Naijiria.

O ni nipasẹ abala iwe ofin irinna Section 325, ko si eeyan titi dori awọn to di ipo oṣelu mu, to kọja ibawi, bi wọn ba tapa si ofin irinna lorilẹede Naijiria.