Yemi Elebuibon ni pé àìmọ̀kan ló ń da Oluwo tí Iwo láàmú nítorí pé kò sí Oba ìsẹ̀mbáyé tó máa pa orírun rẹ́ nílẹ̀ Yorùbá
Kò sí Ọba tó bá jẹ́ ojúlówó ọmọ Oduduwa tó ma ní kí ilẹ̀ Yorùbá má ṣe òrìṣà- Ifayemi Elebuibon
Yemi Elebuibon tó jẹ́ ọ̀kan lara awọn agba to mọ́ asa Yoruba pupo to si wa laye ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lori ohun ti Oluwo n so nipa igbagbọ ati asa Yoruba.
Saaju ni Oba Oluwo ti Iwo, Oba Akanbi Telu 1 ti ni pe oun ju gbogbo orisa ile Yoruba lọ ati pe ko si eyi ti agbara re ju ase ti oun lo.
- Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Russia yóò kógun ja Naijiria àti pé ọmodébìnrin Ukraine gbéná wojú ọmọ ogun Russia?
- Ìwà àìlajú ní Russia hù bó ṣe kọlu ọ̀wọ̀n ìràntí ìṣekúpani - Ukraine
- Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
- Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtìlẹyìn fún Russia àti àwọn tó wà lẹ́yìn Ukraine
- Wo àwòràn ohun tó sẹlẹ̀ ní UKraine
- Kí ló dé tí Esabod àti Lizzy Anjorin fi ń ṣépè fúnra wọn?
Kini Ifayemi Elebuibon fi salaye iwa Oluwo yii fun BBC?
Elebuibon ni pe iwa aimokan lo n da Oba Akanbi laamu.
Agba ọ̀jẹ̀ asà Yoruba, Ifayemi Elebuibon salaye pe Ìlànà wà fún Ọba jíjẹ nílẹ̀ Yorùbá.
Ati pe a lè pe Oluwo ní Ọba ìgbàlódé kìí ṣe Ọba ìtalẹ̀mu ti ko ẹ̀kọ́ yanju fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ osu bi o ti yẹ ki o to joba bi awon Alaafin, Ooni ati Oba Benin to mọ̀ asa se n se.
O ni pe Apá Oluwo kò ká a láti sọ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe òrìṣà mọ́

Imoran wo ni Elebuibon fun Kabiesi Oluwo?
Ni igbeyin, Oloye Ifayemi Elebuibon rọ Kabiesi Oluwo ti Iwo ni ipinle Osun pelu imoran pe ko pada lo kọ́ ẹ̀kọ́ bi o ti ye lori ihuwasi, isọ̀rọ̀si ati isesi Oba alade to jẹ́ ojulowo omo Oduduwa ni awujọ.


