Ìròyìn Kàyééfì BBC Yorùbá: Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ááwọ̀ tó wáyé láárin Oluwo ati Agbowu
Orangun Ila, Oba Wahab Adeniji Oyedotun, ti ni awọn to wa nibẹ nigba ti ija bẹ silẹ laarin ìlú Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi àti ọba Agbowu ti Ogbaagbaa,Dhikrulahi Akinropo ti kọ lati sọ otitọ lori bi ọrọ naa ṣe sẹlẹ.
Orangun to jẹ alaga igbimọ to n pẹẹtu si aawọ laarin Oluwo ati awọn ọba mẹjọ to wa ni ikawọ rẹ sọ wi pe awọn to mọ bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ n bẹru lati sọrọ sita.
O ni bi awọn kan ṣe n sọ wi pe bayii ni ọrọ ri, ni awọn miran n sọ wi pe ọrọ ko ri bẹẹ.
- Ifọrọwerọ Oluwo lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba
- Ènìyàn 65 ló ti ní ààrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Ọsẹ̀ mẹ́ta gbáko lorílẹ́èdè South Afrika yóò fi wà lábẹ́ òfìin kónílé-ó-gbélé
- Ìjọba Ethiopia pàṣẹ pé kí wọ̀n tú ẹ̀gbẹ̀rún mẹ́rin ẹlẹ́wọ̀n silẹ̀ nítorí coronavirus
- Ọ̀ọ̀ni jẹ ọkùnrin kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé nítorí coronavirus mọ́
Eyi lo mu ikọ Kayeefi ti BBC News Yoruba lati lọ ṣe finlẹfinlẹ bi aawọ naa ṣe bẹrẹ ati ohun to faa.
Ẹkunrẹrẹ alaye wa ninu fidio yii.