Esabod/Lizzy Crisis: Esabod ní Ọlọ́run Toyin Abraham tó gbè é níjà ní kí aráyé máa sìn

Oríṣun àwòrán, Esabod/ Lizzy/Instagram
Se ni ori ayelujara tun n gbona jainjain bayii nitori aawọ to n waye laarin gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara nni, Esther Tokunbo Aboderin, ti ọpọ mọ si Esabod.
Oun ati ilumọọka osere tiata miran Lizzy Anjorin si ni wọn dijọ doju kọ ara wọn lori ayelujara eyi to ya ọpọ eeyan lẹnu.
Ọpọ eeyan lo mọ awọn gbajumọ yii bii ẹni mọ owo lori ayelujara nitori pe amuludun ni wọn, ti awọn mejeeji si sun mọ ara wọn pẹki pẹki.
- Wèrè tí mò ń ṣe ní Facebook ló pawó fún mi-Esabod
- Gìrì àparò lásán ni gbogbo èpè wọn! àwọn tó ń ti Toyin Abraham lẹ́yìn rèé lórí ìjà tó paá pọ́ mọ́ Lizzy Anjorin ati ESABOD
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- ESABOD gbé ìjà Mide Martins rù sórí ara rẹ̀ ó ń fi èpè ránṣẹ́ sí Adunni Olorisa àtàwọn míì
- Lẹ́yìn ọdún méjì tí iná ìjà tí n jó láàrin wọn, Lizzy Anjorin sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Toyin Abraham ṣẹ̀ ẹ́
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
Idi si ree ti ọpọ eeyan se n kọ haa hin pe ki lo le fa ija laarin awọn 'ọrẹ meji' yii, ti wọn ti sun mọ ara wọn pẹki pẹki.
Ki lo fa ija laarin Lizzy Anjorin ati Esabod:
Esabod n sepe fun mi tori pe n ko ki ku ọjọ ibi ọgọta ọdun:
Nigba to n salaye ohun to fa aawọ laarin awọn mejeeji loju opo Facebook, Lizzy Anjorin salaye pe ija aikini ni ọjọ ibi lo wa laarin awọn mejeeji.
Lizzy ni oyun osu mẹjọ lo wa ninu oun lọjọ Kẹrindinlọgbọn osu kẹta ọdun 2021 ti Esabod n se ọjọ ibi ọgọta ọdun.
O salaye pe ọjọ naa si ni oun n rinrin ajo lọ si Florida lati lọ bi ọmọ oun, ti oun si gbagbe pe ọjọ naa ni ọjọ ibi ọgọta ọdun Esabod.
O salaye pe bi oun ko se gbe obinrin naa si oju opo ayelujara oun lati ki ku ọjọ ibi lo sokunfa wahala naa, to si n bọ sori ayelujara lati ki oun.
Esabod n gbe ọkunrin fun mi ki wọn le ka ajọsepọ wa silẹ:
Bakan naa ni Lizzy Anjorin tun tẹsiwaju pe akoko kan wa ti Esabod ni ki oun wa ra ile ni Turkey, to si n tiraka lati gbe ọkunrin fun oun.
O ni ti kii ba se pe oun ti gbọn ni, erongba rẹ ni lati ka ajọsepọ oun ati ọkunrin naa silẹ, ko si gbe sori ayelujara.
Lizzy fikun pe ọpọ igba ni Esabod ti sọ pe ki oun gbe awọn eeyan to n bu oun lori ayelujara lọ sile ẹjọ, amọ ti yoo pada maa sọ pe oun kii gbọran.
Esabod gba aimọye owo lọwọ mi, mo kabamọ ọjọ ti mo pade rẹ:
Bakan naa ni Lizzy tun fi ẹsun kan Esabod pe o gba ọpọ owo lọwọ oun, ko to da si aawọ oun ati Toyin Abraham.
O ni se ni Esabod n gba owo lọwọ oun lati maa fi ori oun ati Toyin Abraham gba ara wọn, to si di aawọ nla.
O ni oun ati Toyin ko nija, ọmọ kekere ni awọn mejeeji dijọ gbe dani amọ Esabod lo n da ija silẹ laarin awọn.
Lẹyin naa ni Lizzy wa ki ọpọ epe mọlẹ, to si n rọ ojo rẹ sori Esabod eyi to kọja sisọ.
Toyin Abraham, jọọ ma binu, ori rẹ ti mu emi ati Lizzy Anjorin:
Nigba to n fesi lori gbogbo ohun ti Lizzy sọ lori ayelujara, Esabod ni wahala Lizzy ti pọ ju nipa ko maa ba ọpọ eeyan ja, ni oun se sa fun.
O ni lootọ ni oun ati Lizzy dijọ ditẹ mọ Toyin Abraham amọ ori rẹ ti mu awọn mejeeji ni ija se bẹ silẹ laarin awọn.
O wa tọrọ aforijin lọwọ Toyin Abraham pe ko ma binu lori gbogbo awọn aidaa ti oun ti hu si.
Bakan naa lo tun sọ pe ki ọpọ eeyan beere iru Ọlọrun ti Toyin Abraham n sin, ki wọn le maa sin, nitori Ọlọrun rẹ ti gbe nija.
Esabod ni ọpọ ibajẹ awọn osere tiata ni Lizzy ti se fun oun amọ ti oun kọ lati da si ọrọ naa.
Bakan naa ni Esabod tako Lizzy pe oun ko figba kankan gba owo lọwọ rẹ, to ba si jẹ pe lootọ ni ohun to n sọ, ko mu ẹri to daju jade.
Kii se Lizzy Anjorin lo bi Florida to n pe ni ọmọ rẹ:
Esabod tun tẹ siwaju lori awọn ọrọ to sọ loju opo ayelujara rẹ pe kii se Lizzy lo bi ọmọ to to wa lọwọ rẹ.
Esabod ni akọbi Lizzy, eyiun Rotimi lo loyun, to si gbe lọ silẹ Amẹrika lati bimọ ti Lizzy si gbe ayederu oyun sinu.
O wa fi aworan awọn ọmọ mejeeji naa han sode, to si ni wọn jọ ara wọn ju baba to ni oun bimọ fun lọ.
Ko tan sibẹ, oniruuru epe ni Esabod naa fi ransẹ si Lizzy nitori aawọn to wa ni aarin awọn mejeeji.
Bakan naa ni Esabod kede pe osere tiata naa ni ọkunrin miran ni Florida to ti lọ bimọ, to si ni ko fi awọn ọmọ rẹ re, ti ko ba ri bẹẹ.
Ki lo sun Esabod ati Lizzy Anjorin pade ara wọn:
Ni bii ọdun melo kan sẹyin, aawọ ti wa laarin osere tiata miran, Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin, ti wọn dijọ jẹ osere tiata.
Ija naa gbona gidi lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si pari rẹ ti, koda o tun buru jai nigba ti Toyin Abraham bimọkunrin.
Bakan naa tun ni ija naa tun fọn ina soju nigba ti Lizzy Anjorin bimọbinrin ni ọdun 2021, ti ọpọ ololufẹ awọn osere tiata mejeeji si dijọ n gbena woju ara wọn.
Asiko yii si ni gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara, ESABOD da si aawọ yii, to si gbiyanju lati pari aawọ laarin awọn mejeeji.
Ori ayelujara naa tun pada gbona nitori igbesẹ pipari aawọ naa tun gbọna miran yọ, eyi to mu omi loju Toyin Abraham.
Idi ni pe Toyin ni Esabod n sẹ epe fun ọmọ oun, ti ọpọ ololufẹ osere tiata naa si bọ sita lati tako igbesẹ Esabod naa.
Sugbọn lẹyin o rẹyin, Esabod pada pari ija naa, ti eruku aawọ naa si lọ silẹ.
Sugbọn iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan pe Lizzy ati Esabod pada wa doju ija kọ ara wọn, ti Toyin Abraham ko si tii fesi kankan titi di akoko yii lori ọrọ naa.




















