Road accident: Tírélà tẹ ẹ̀ṣọ́ àjọ FRSC pa lọ́nà Sagamu sí Ijebu Ode

Oríṣun àwòrán, @Others
Ẹṣọ ajọ oju popo, FRSC ti ṣe a fi agbako iku ojiji lẹnu iṣẹ loju popo ilu Sagamu si Ijebu Ode.
Ọga agba ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar lo fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin NAN niluu Abeokuta.
Umar ṣalaye pe ere aṣaju dẹrẹba ọkọ tirela lo ṣokunfa ijamba naa.
- Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife
- Èyí ni ìdí tí Bàbá Kérésì fi máa n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo
- Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà
- Ẹ fura àwọn agbésùmọ̀mi láti Mali fẹ́ wọ ìlú Abuja
- Ọ̀fẹ́ ni ọkọ̀ ojú irin akérò yóò máa kó àwọn arìnrìnàjò lásìkò pọ̀pọ̀ṣìnṣin ọdún yìí - Ìjọba àpapọ̀
- Àjọ aṣọ́bodè gbẹ́sẹ̀ lé òògùn ìbálòpọ̀ ẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù ní ìpínlẹ̀ Katsina
Umar ni "aibikita ati ere aṣaju awakọ tirela naa lo jẹ ko kọlu ọkan lara awọn ẹṣọ FRSC to wa loju popo.
Awọn ẹṣọ oju popo duro lẹgbẹ ọkọ FRSC ti wọn fi n ṣiṣẹ ki tirela ọhun ti fi ẹgbẹ gba ọkan lara wọn ti ọkunrin naa si ku ti omiran si farapa.
Awakọ tirela ọhun ko tiẹ duro lẹyin to kọlu awọn ẹṣọ FRSC naa tan.
Awọn awakọ mii at'awọn to gun alapupu ti iṣẹlẹ naa soju wọn lo ṣẹṣẹ le e mu.
Awakọ tirela naa fi ọkọ to n wa silẹ nigba ti wọn mu un, o si salọ.
Ṣugbọn wọn rí mu un wọn si ti jọwọ rẹ fawọn ọlọpaa.
Ẹsọ oju popo to ṣeṣe nibi ijamba naa ti n gba ìtọjú nile iwosan,"ọga ajọ FRSC ṣalaye.
















