Russia-Ukraine Crisis: Amẹ́ríkà fọnmú pé yóò burú jáì fún China tó bá ran Russia lọ́wọ́ lórí ìkọlù sí Ukraine

Ibudo kan ti ado oloro bajẹ ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Amẹrika ti n lọgun tantan fun gbogbo araye bayii pe ki wọn fi ewe ọmọ mọ orilẹede China leti pe ko mase seto iranwọ kankan fun ilẹ Russia lori ogun to n gbe ti orilẹede Ukraine.

Amẹrika ni ti orilẹede China ba fi gbe igbesẹ naa, a jẹ pe ọrọ naa yoo lẹyin, bii oku iya jọjọ fun wọn.

Awọn asaaju ilẹ Amẹrika kan, ti wọn ko darukọ wọn, lo laago ikilọ yii fawọn oniroyin pe orilẹede Russia ti n rọ ilẹ China lati pese iranwọ ologun fun oun lẹyin to bẹrẹ ikọlu rẹ si Ukraine.

Amọ ileesẹ asoju ilẹ China to wa lorilẹede Amẹrika ti kede pe oun ko mọ nipa eto iranwọ ologun ti wọn ni Russia n beere lọwọ orilẹede oun.

Ilẹ Amẹrika si lo ti wa n dunkooko pe apẹyinda to buru jai ni igbesẹ iranwọ naa yoo ni fun orilẹede China to ba fi se bẹẹ.

Alasẹ China

Oríṣun àwòrán, EPA

Idunkooko orilẹede Amẹrika yii si lo n waye saaju ipade ti yoo waye nilu Rome laarin awọn asaaju orilẹede AMẹrika ati China loni ọjọ Aje.

Lati igba ti ogun Russia ati Ukraine yii si ti bẹrẹ, ni orilẹede China tun ti fidi atilẹyin ọlọjọ pipẹ rẹ fun orilẹede Russia mulẹ.

Amọ ti ko han si araye boya o ti seto iranwọ ologun tabi ti ọrọ aje fun ilẹ Russia lasiko ogun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn awọn ileesẹ iroyin labẹle ni Amẹrika lo ti n kede pe laipẹ yii ni orilẹede Russia ti n beere awọn ohun eelo ijagun, to fi mọ baalu ijagun lọwọ China.

Titi di akoko yii, orilẹede China China ko tii fesi lori awọn ẹsun naa.