Yoruba Nation: Akintoye ní Sunday Igboho kò gbọdọ̀ sojo torí kò sí ajìjàgbara tí kò rí ìfìyàjẹni

Ọjọgbọn Banji Akintoye, Sunday Igboho ati Ọjọgbọn miran

Oríṣun àwòrán, Maxwell Adeleye

Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua (IOO) to n jijagbara fun ominira ilẹ Yoruba ti n dunkooko pe ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba yoo bẹrẹ pada lọsẹ yii.

Asaaju ẹgbẹ IOO, Ọjọgbọn Banji Akintoye lo sisọ loju ọrọ naa lasiko to n ba iwe iroyin Saturday Sun sọrọ lori igbesẹ to kan ti wọn yoo gbe lẹyin itusilẹ Sunday Igboho.

Bẹẹ ba gbagbe, Sunday Igboho ni ileẹjọ kan ni orilẹede Benin fun ni idande lọgba ẹwọn lati lọ tọju ara rẹ, lai jade kuro lorilẹede naa tabi kopa ninu ijija gbara kankan.

Nigba to n dahun ibeere naa, Akintoye, ẹni ti akọwe ẹgbẹ IOO, Maxwell Adeleye gbẹnu sọ fun tun kede nipa ilana to kan ti wọn yoo gbe.

O ni loni ọjọ Aiku ni ẹgbẹ Ilana Omo Oodua yoo se agbekalẹ awọn ilana to kan ninu ipe wọn fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè i

Sunday Igboho kò gbọdọ̀ sojo torí kò sí ajìjàgbara tí kò foju wina ìfìyàjẹni:

O fikun pe pẹlu gbogbo agbara ni awọn yoo fi beere fun ijijagbara fun ominira iran Yoruba lasiko yii.

"Ogun to gbọdọ tẹ siwaju ni, a si lo ilana ofin ati isẹ ọpọlọ ta ni lati ri daju pe afojusun wa naa jọ.

Ẹ sa duro di ọjọ Aje fun ikede awọn igbesẹ to kan."

Nigba to n sọrọ lori ominira ranpẹ ti ile ẹjọ fun Sunday Igboho, Akintoye ni ajijagbara naa ti di akọni nla.

Amọ o wa gba Igboho nimọran lati mase jẹ ki ipenija to koju rẹ da omi tutu si lọkan lati tẹsiwaju ninu ijagudu rẹ fun ominira iran Yoruba.

"Ijagudu ni, tile ẹjọ si ti kede pe o ba ofin mu. Nitorinaa, ko gbọdọ rẹwẹsi ninu ijagudu naa nitori ko si awọn ajijagbara jakejado agbaye ti wọn ko foju wina ifiyajẹni.

Se lo yẹ ko jẹ ki ireti rẹ ninu ijijagbara naa si maa gbona gidi , ko si mu amusẹ erongba awọn eeyan rẹ lọkunkundun."

Nigba to n sọrọ lori ipo ilera Sunday Igboho, Akintoye wa fọwọ idaniloju sọya pe ajijagbara naa ti n gba itọju bo se yẹ lẹyin to gba idande kuro lọgba ẹwọn tan.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

Ki lo sẹlẹ sẹyin:

Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii aago kan oru ni DSS kọlu ile Igboho to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, iyẹn lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun to kọja.

Ikọlu naa lagbara to bẹẹ ti ẹmi eeyan meji sọnu, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran, amọ Igboho moribọ.

Ẹwẹ, lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021 kan naa ni Igboho ti wa lọgba lorilẹ-ede Cotonou, ti ijọba orilẹ-ede naa ko si fi ẹsun kankan kan an.

Amọ o ri ile ẹjọ kan ni Cotonou lorilẹede olominira Benin ti wa fun ni idande pe lọgba ẹwọn lati lọ tọju ara rẹ, lai jade kuro lorilẹede naa tabi kopa ninu ijija gbara kankan.