Sunday Igboho: Òfin ilẹ̀ adúláwọ̀ kò fún ìjọba láṣẹ́ láti gbé Igboho kúrò ní Cotonou fún ìdí kankan

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Agbẹjọro fun oloye Sunday Igboho ti sapejuwe bi ikọ ọlọpa INTERPOL se mu onibara rẹ nilu Cotonou lorilẹede Benin bii eyi to ba ni lojiji.

Atẹjade kan ti amofin Yomi Aliyu fi ransẹ si BBC Yoruba lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe yoo dara ki awọn ọlọpa agbaye INTERPOL mọ nipa igbesẹ tawọn DSS ti kọkọ gbe saaju nipa kikọlu ile Igboho, ti wọn si pa eeyan nibẹ pẹlu biba ọpọ dukia jẹ.

Aliyu ni Awọn DSS ko ri ohunkohun to lodi sofin nile Sunday Igboho amọ wọn pa eeyan meji, ti wọn si gbe oku wọn lọ, ti wọn si ko ibọn meji to jẹ ti ẹsọ Adisa Saheed Olalekan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ni wọn se afihan eeyan mẹtala ti wọn ko nile naa, ti onibara oun si ti ni oun ko mọ ohunkohun nipa awọn ohun ija ti DSS se afihan rẹ pe wọn ko nile oun.

"O ti wa ni akọsilẹ pe awọn ibọn ti DSS patẹ rẹ yii ni DSS ti patẹ rẹ saaju lọdun 2013 ninu isẹlẹ miran, to si wa loju opo Facebook lọdun 2013 bi o tilẹ jẹ pe DSS ti pa a rẹ loju opo ayelujara rẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Ọkan lara awọn eeyan ti wọn pa naa, Saheed Adisa Olalekan lo ni ile itaja Oladams Motors, Osogbo, o si wa sile Igboho lati jiroro lori katakara ọkọ ni.

O wa pẹlu ẹsọ ọlọpaa meji, bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹsọ ọlọpaa naa ko si lara awọn eeyan ti DSS foju wọn han faraye, ti ibọn wọn meji si wa lara ibọn ti DSS patẹ rẹ."

Agbẹjọro Sunday Igboho wa tọkasi pe adehun to wa laarin orilẹede Naijiria, Togo, Ghana ati orilẹede Benin ko fi ọwọ si pe ki wọn gbe ẹni to n sa lọ tori ọrọ oselu.

O ni ofin ọhun lo sọ pe orilẹede ti ẹni to n sa lọ ba wa le ma fi onitọun silẹ nitori idaduro to wa ninu eto idajọ tabi nitori idẹyẹsi.

Bakan naa lo ni abala ofin ẹtọ ọmọniyan ẹsẹ ogun ninu ofin ilẹ adulawọ ti awọn orilẹede mẹrẹẹrin naa fọwọsi ni gbogbo wọn lo gbọdọ daabo bo ẹtọ fun ijijagbara.

Àkọlé fídíò, Philosophy of Ori: Olatunji ní orí ẹni ló ń dúró ti ní lọ́jọ́ ìṣòro àti lójú ikú

"Ofin yii lo mu ki Oloye Sunday Igboho jẹ ẹlẹsẹ nidi oselu, ti wọn ko le gbe ni apayanka wale tabi gbe kuro nilẹ Benin Republic fun idi kankan.

Koda, wọn mu aya Sunday Adeyemo, Ropo , tii se ọmọbibi orilẹede Germany pẹlu rẹ ni Cotonou, iru ẹsẹ wo ni oun naa sẹ ti wọn fi mu?"

Amofin Aliyu wa n rọ ijọba orilẹede Benin ati awujọ agbaye, paapaa orilẹede Germany lati dide pinwọ iwa ta ni yoo mu mi tijọba Naijiria n hu.

O ni ki awujọ agbaye kọ lati gba ẹbẹ ijọba lati gbe onibara oun kuro ni Cotonou nitori o ti pe ẹjọ saaju niwaju ileẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran, ICC.