Portable Zazzu: Ẹni tó já mi sí ìhòhò pé mo gbé márúwá àti iPhone, ló ní máà kú láàrin ọjọ́ méje

Portable ọmọ Olaolomi

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/nstagram

Yoruba ni eeyan kii gbọ ọjọ iku rẹ ko dakẹ, bẹẹ ni eeyan kii mọ ẹni ti yoo pa, ko fi oju rere wo.

Idi ree ti gbajugbaja akọrin Zazzu Zeh, Habeeb Olalomi, ti ọpọ eeyan ni Portable se figbe ta pe awọn eeyan kan fẹ pa oun.

Portable, ẹni to pariwo iku ara rẹ tantan tan ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ ni ọjọ meje pere ni wọn sọ fun oun pe o ku fun oun lati laye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye pe wọn ti ba gbogbo mọto oun jẹ, ti wọn si tun n halẹ iku mọ oun.

Ki lo wa laarin Portable ati ẹni to ni o fẹ pa oun:

Nigba to n salaye ohun to pa oun ati ẹni to fi ẹsun kan naa papọ, Portable ni igba akọkọ kọ ree ti ẹni naa yoo dunkooko mọ ẹmi oun.

Akọrin Zazzu naa ni losu Kejila ọdun to kọja ni ẹni naa parọ mọ oun pe oun ji kẹkẹ Maruwa ati iPhone, ti wọn ja oun si ihoho.

O ni lasiko yii ẹni naa tun ni oun yoo pa oun laarin ọjọ meje.

Portable wa n salaye pe ẹni to fẹ pa oun yii ni oun kọkọ lọ sọdọ rẹ pe ko gbe awo orin oun jade, to si tibẹ lu aluyọ lai fun oun ni ohunkohun ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Janduku da Portable lọna ni ọjọ ibi rẹ:

Gbajumọ akọrin naa, to sami ọjọ ibi rẹ ni ọjọ Satide, ọjọ Kejila osu kẹta ọdun 2022, ni iroyin kede pe awọn janduku kan da lọna.

Fidio kan to gba ori ayelujara kan lo sisọ loju ọrọ naa.

Ninu fidio naa si ni ariwo ti gbalẹ kan laarin Portable atawọn ọmọ isọta ọhun, to si n pariwo pw ta ni ọga wọn.

Ohun ti wọn si lo fa ariwo naa ni bi Portable se kọ lati sanwo ilẹ to fẹ gba kọja fawọn janduku naa.

Iroyin naa ni wọn fi ọwọ ba akọrin yii ati awọn eeyan to tẹle, ti oun naa si fidi rẹ mulẹ pe wọn ba gbogbo mọto ti oun gbe jade jẹ.

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, akọrin zazzu naa ni wọn lo sọ fawọn janduku naa pa ki wọn lọ mu ọga wọn wa fun oun nigba ti wọn n beere owo lọwọ rẹ.

A gbọ pe idi ree ti wọn se kọju ija si, ti wọn si ba awọn gilaasi ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo