Abba Kyari Money Laundering: Agbẹjọ́rò àgbà Naijiria sọ pé kò sí ẹ̀rí tó fihàn pé Kyari jẹ̀bi

Abba Kyari ati Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Daily Nigerian

Ọrọ tun ti gba ọna miran yọ bayii lori ẹsun kiko owo pamọ lọna aitọ fun awọn onijibi ti wọn fi kan ọga agba nigba kan fun ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa, Abba Kyari.

Minisita fun eto idajọ, to tun jẹ agbẹjọro agba fun Naijiria, Abubakar Malami, ti sọ pe ko si ẹri to fihan pe Kyari jẹbi ẹsun kiko owo pamọ lọna aitọ.

Oṣu Keje, ọdun to kọja ni wọn da Kyari, to ti fi igba kan jẹ igbakeji kọmisanna ọlọpaa, duro, fun ẹsun pe o kopa ninu bi ogbontagi gbajuẹ ori ayelujara, Ramon Abass Hushpuppi, ṣe lu jibiti to le ni miliọnu kan Dọla.

Bakan naa lo tun n koju ẹsun pe o lọwọ si tita oogun oloro. O n jẹjọ lọwọ nile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja.

Ṣaaju ni Malami sọ ninu oṣu Kinni pe, iwadii tileeṣẹ ọlọpaa sẹ fihan pe Kyari jẹbi ẹsun kiko owo pamọ, lẹyin iwadii to waye lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Hushpuppi.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

To si paṣẹ fun ọga agba ọlọpaa pe ko tubọ ṣe iwadii lori awọn owo ti Kyari jere ninu iṣẹ jibiti.

Iha tuntun ti agbẹjọro agba kọ si ọrọ Kyari, jẹyọ ninu lẹta an to fi ranṣẹ si ọga agba ọlọpaa pe, ko si aridaju tabi ẹri to fihan pe lootọ ni awọn owo kan ti wọn tọpinpin rẹ de awọn apo asunwọn kan ni banki, ko ni nkankan ṣe pẹlu Abba Kyari.

Gẹgẹ bi iwe iroyin abẹle The Punch ṣe jabọ, MAlami sọ pe awọn eeyan mẹrin to ni awọn apo asunwọn naa lo ni owo, ti wọn si na owo naa fun'ra wọn.

Malami ṣalaye pe awọn onithun jẹri pe Kyari ko mọ tabi ni nkankan ṣe nipa owo naa.

O ni lootọ ni Kyari jẹbi awọn ẹsun kan ti ileeṣẹ ọlọpaa le ba a wi si - o dọrẹ pẹlu awọn afurasi onijibiti, eyi to tako iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, hushpuppi

Àkọlé àwòrán, Hushpuppi gbajumọ pupọ lori ayelujara nitori boṣe ma n ṣafihan awọn dukia olowo iyebiye ki ọwọ ọlọpaa ilu Dubai to tẹ ẹ lọdun 2020

Bakan naa lo sọ pe wọn tun le ba a wi nitori pe o tapa si ofin ileeṣẹ ọlọpaa to de lilo oju opo ibaraẹnidọrẹ lori ayelujara, nipa bo ṣe fesi si ẹsun jibiti ti ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America, FBI, fi kan lori Facebook.

Ati boṣe fi afurasi kan, Vincent Chibuzor si ahamọ ju oṣu kan lọ lai gba aṣẹ nile ẹjọ.

Ajọ to n mojuto eto igbẹjọ, DPP, ṣalaye pe iha tuntun ti Malami kọ si ọrọ Kyari, ko ṣẹyin abọ iwadii ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe.

O ni awọn kudiẹkudiẹ kan wa nibẹ.

Ajọ naa sọ pe kii sẹ pe awọn ni ko jẹbi, ṣugbọn awọn sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe ko sẹ iwadii miran nitori eyi to kọkọ ṣe ko fihan pe Abba Kyari jẹbi ẹsun kikowo pamọ lọna aitọ.

" A sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn o ṣiṣẹ lori awọn kudikudiẹ ti a ri ninu iwadii wọn, ṣugbọn wọ kọ̀."

Ṣaaju iṣẹlẹ yii, ẹni ọwọ ati apnle ni Abba Kyari jẹ nileeṣẹ ọlọpaa, paapaa fun ipa to ko ninu igbogun ti ijinigbe lorilẹ-ede Naijiria.