Sunday Igboho: Ẹ̀yin alátilẹ́yìn mi, ìjíròrò ló kù fún òmìnira báyìí kìí se ogun rárá

Oríṣun àwòrán, @Sunday Igboho
Sunday Igboho ti gbogbo eeyan mo si Igboho Oosa fi imoore han si awon alatilẹ̀yin rẹ̀ o tun kọ̀ ogun jija.
Oloye Sunday Adeyemo dupe pupọ́ lọ́wọ́ alaga ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua, Ojọ́gbọ́n Banji Akintoye ati Ojogbon Wale Adeniran ati awon ọmọ Naijiria lapapo to n satileyin.
Amofin Yomi Aliyu to jẹ́ agbẹjọ́rò fun Sunday Igboho lo sọ eyi di mimo ninu atejade to fi sita bayii.
Yomi Aliyu ni pe Sunday Igboho si n tesiwaju lati waasu lodi si ogun.
- Ìjọba ìpínlẹ Eko ti lé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW kúrò ní gáréèjì ọkọ̀
- 'Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Sunday Igboho kò sì lè kúrò ní Benin Republic, sùgbọ́n ó tí kúrò ní àhámọ́ lọ gba ìtọ̀jú nílé ìwòsàn níbẹ̀- Agbẹjọ́rò Sunday Igboho
- Wọ́n ti rí òkú obìnrin ẹni ọdún 22 tó dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko
- Ọkọ̀ tó rìn gba "one way" gbá ọmọ ìyá mẹ́rin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo l'Eko, ọ̀kan kú
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀
Kini Igboho tun so?
Sunday Igboho tun parọwa fun gbogbo awọn ajijangbara pe agbara wa ninu ijiroro ati asoyepo lai yinbon rara.
O menuba ipo ẹlẹgẹ́ ti alaafia wa lasiko yii ni orikle-ede Naijiria.
Awon mii wo lo tun dupe lọ́wọ́ wọn?
Igboho Oosa tun fi imoore han fun awon bii Dele Momodu atawon mii to wa woo ni atimole ni Cotonou.
O dupe lowo Aare Talon to n tuko orile-ede Benini Republic to tu oun sile nlati wa pelu awon molebi oun ni Cotonou lasiko yii.
O tun dupe lọ́wọ́ agbejọ́ro Yomi Aliyu atawon to ku.
Ileri wo ni Igboho se lati tesiwaju?
Sunday Igboho fi da won ololufe rẹ̀ loju pe oun yoo tesiwaju ninu ija ominira ati ijijangbara ile Yoruba.
O fi idaniloju fawon to feran alaafia pe oun ko ni pada seyin ninu ija ife ati ominira.

Oríṣun àwòrán, Anike Iyaniwura TV
Nitori aisan kọ ni wọn fi tu Sunday Igboho silẹ l'ọgba ẹwọn.
Orísi ìgbésẹ̀ lá gbé kí ọ̀rọ̀ Igboho tó já sí ọ̀pẹ́ yìí, díẹ̀ rèé lára wọn- Amofin Falola
Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si 'Sunday Igboho', Amofin Falọla Maleek Oluṣegun ti ṣe alaye pe ni alaafia ara ni Igboho jade ni ọgba ẹwọn lẹyin oṣu meje ti o ti wa nibẹ.
O ni lootọ ni ajafẹtọmọniyan na ṣe aisan ni ọgba ẹwọn, ṣugbọn nitori eleyii kọ ni wọn ṣe fun un ni ominira.
- 'Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lásíkò àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Timothy Adegoke: Ìyàwó Timothy Adegoke jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́, gbọ́ nípa ìjà tó jà fún ọkọ̀ rẹ̀
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí lílo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi ti padà kú o!
Falọla ni ijọba orilẹede Benin pinnu lati yọ Igboho kuro ni ahamọ nitori pupọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni ko fi ẹsẹ mulẹ.
Botilẹ jẹ wi pe iṣẹ iwadii ti ijọba ilẹ naa n ṣe ṣi n tẹsiwaju, amofin yii ni wọn ko ri iredi kan lati sọọ si ahamọ.
Sunday Igboho ti kuro ni ọgba ẹwọn bayii, ṣugbọn yoo ṣi wa ni orilẹede Benin titi ti ijọba ilẹ naa yoo fi yọri iṣẹ iwadii ti wọn n ṣe. Lẹyin eyii ni Igboho yoo ni anfani lati fi orilẹede naa silẹ.
Falọla fi idi rẹ mulẹ pe ayọ ọkan Sunday Igboho ko ṣee royin lori anfani ti wọn fun un lati kuro ni ahamọ lẹyin oṣu meje.
Ati eleyii ṣi fi ara han ninu awọn aworan ati fọnran ti Igboho fi lede lori itakun ayelujare lẹyin ti o kuro lọgba ẹwọn.
Falọla ni awọn agbẹjọrọ mẹwa ọtọọtọ lo gba iṣẹ lori ọrọ Sunday Igboho nigba ti ẹjọ naa bẹrẹ, ṣugbọn awọn mẹrin pere lo ku si ẹnu rẹ bayii.
Oni awọn agbẹjoro ni anfani lati yọwọ ninu eyikeyi ẹjọ ti o ba ti yọ ni ọkan wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe oun ni ẹlẹẹkẹrin ninu awọn agbẹjọro to ṣiṣe fun ominira Sunday Igboho.
Awon Amofin wo ni wọ́n jọ sise yo Sunday Igboho kuro ni ahamọ́?
Lara awọn to ku ni Amofin Salami, Kato, ati Raphael.
Falọla ti o n gbe nile okeere fi idi rẹ mulẹ wi pe awon ololufẹ Sunday Igboho ni orilẹede naa lo gbe iṣẹ fun oun gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbẹjọro ti yoo ṣoju Igboho lati France.
O parọwa si awọn akoroyin lati maa ṣe iwadii ti o daju ki wọn to maa fi iroyin lede.





























